April 12-18
NỌ́ŃBÀ 20-21
Orin 114 àti Àdúrà
Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
“Jẹ́ Oníwà Pẹ̀lẹ́ Kódà Nígbà Tí Kò Bá Rọrùn”: (10 min.)
Àwọn Ìṣúra Tẹ̀mí: (10 min.)
Nọ 20:23-27—Kí la rí kọ́ látinú bí Áárónì ṣe hùwà pa dà nígbà tí Jèhófà bá a wí àti ojú tí Jèhófà fi wo Áárónì láìka àṣìṣe rẹ̀ sí? (w14 6/15 26 ¶12)
Àwọn ìṣúra tẹ̀mí wo lo tún rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí nípa Jèhófà, iṣẹ́ ìwàásù tàbí àwọn nǹkan míì?
Bíbélì Kíkà: (4 min.) Nọ 20:1-13 (th ẹ̀kọ́ 2)
MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ
Nígbà Àkọ́kọ́: (3 min.) Lo ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ. Onílé sọ ohun táwọn èèyàn sábà máa ń sọ tí wọn ò bá fẹ́ gbọ́ ìwàásù. Fèsì ní ṣókí, kó o sì máa bá ọ̀rọ̀ rẹ lọ. (th ẹ̀kọ́ 12)
Ìpadàbẹ̀wò: (4 min.) Bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ. Fún un ní ọ̀kan lára àwọn ìtẹ̀jáde tó wà nínú Àpótí Ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́. (th ẹ̀kọ́ 3)
Àsọyé: (5 min.) g 3/15 9—Àkòrí: Bó O Ṣe Lè Kápá Ìbínú Rẹ? (th ẹ̀kọ́ 16)
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Máa Sọ “Ọ̀rọ̀ Tó Ń Gbéni Ró” Fáwọn Míì: (7 min.) Ìjíròrò. Jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò náà. Lẹ́yìn náà, béèrè àwọn ìbéèrè yìí: Tá a bá ń sọ̀rọ̀ ìbàjẹ́ tàbí tá à ń ráhùn, báwo nìyẹn ṣe lè ṣàkóbá fáwọn míì? Kí ló ran arákùnrin yẹn lọ́wọ́ láti ṣe àtúnṣe tó yẹ?
Má Ṣe Jẹ́ Kí Àwọn Ẹgbẹ́ Ẹ Ba Ìwà Ẹ Jẹ́!: (8 min.) Ìjíròrò. Jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò eré ojú pátákó náà. Lẹ́yìn náà, béèrè àwọn ìbéèrè yìí: Àwọn nǹkan wo làwọn èèyàn lè fúngun mọ́ wa láti ṣe? Ìmọ̀ràn wo ló wà nínú Ẹ́kísódù 23:2? Àwọn nǹkan mẹ́rin wo la lè ṣe táwọn ojúgbà wa ò fi ní mú ká ṣe ohun tí kò dáa?
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: (30 min.) rr orí 7 ¶16-23
Ọ̀rọ̀ Ìparí (3 min.)
Orin 129 àti Àdúrà