ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
Jẹ́ Oníwà Pẹ̀lẹ́ Kódà Nígbà Tí Kò Bá Rọrùn
Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Mósè nínú aginjù mú kó nira fún un láti jẹ́ oníwà pẹ̀lẹ́ (Nọ 20:2-5; w19.02 12 ¶19)
Láàárín àkókò kan, Mósè ṣe ohun tó fi hàn pé kò ní ìwà pẹ̀lẹ́ (Nọ 20:10; w19.02 13 ¶20-21)
Jèhófà bá Mósè àti Áárónì wí torí àṣìṣe ńlá tí wọ́n ṣe (Nọ 20:12; w09 9/1 19 ¶5)
Ẹni tó ní ìwà pẹ̀lẹ́ kì í tètè bínú, kì í gbéra ga, kì í sì í mọ tara ẹ̀ nìkan. Táwọn èèyàn bá tiẹ̀ múnú bí i, ó máa ń ní sùúrù, kì í gbaná jẹ, kì í sì í fi ibi san ibi.