Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ | JẸ́ KÍ IṢẸ́ SÍSỌNI DI ỌMỌ Ẹ̀YÌN MÁA FÚN Ẹ LÁYỌ̀

Máa Lo Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run

Máa Lo Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run

Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lágbára! (Heb 4:12) Kódà, ó lè wọ àwọn tí kò mọ Ọlọ́run lọ́kàn. (1Tẹ 1:9; 2:13) Inú wa máa ń dùn gan-an tá a bá rí bí ẹni tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ ṣe ń mọyì ohun tuntun tó ń kọ́ látinú Bíbélì.

Ẹ WO FÍDÍÒ NÁÀ JẸ́ KÍ IṢẸ́ SÍSỌNI DI ỌMỌ Ẹ̀YÌN MÁA FÚN Ẹ LÁYỌ̀​—TÚBỌ̀ JÁ FÁFÁ​—JẸ́ KÍ ÀWỌN ÈÈYÀN RÍ AGBÁRA TÍ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN NÍ, KẸ́ Ẹ SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:

  • Kí ni Neeta sọ tó jẹ́ kí Jade rí i pé ó bọ́gbọ́n mú kí wọ́n ká Bíbélì?

  • Báwo ni Neeta ṣe jẹ́ kí Jade rí agbára tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ní nígbà tó ní kí Jade ka ẹsẹ Bíbélì yẹn sókè, tó sì mẹ́nu kan kókó pàtàkì tó wà níbẹ̀?

  • Kí ló fi hàn pé ẹsẹ Bíbélì yẹn wọ Jade lọ́kàn, báwo nìyẹn sì ṣe rí lára Neeta?