Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Pétérù àti Jòhánù ń ṣètò yàrá òkè tí wọ́n ti fẹ́ ṣe Ìrékọjá ọdún 33 S.K.

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Ṣé Ò Ń Múra Sílẹ̀ fún Ìrántí Ikú Kristi?

Ṣé Ò Ń Múra Sílẹ̀ fún Ìrántí Ikú Kristi?

Ìrékọjá tí Jésù ṣe kẹ́yìn ṣàrà ọ̀tọ̀ gan-an. Torí pé kò ní pẹ́ kú, ó ṣètò láti jẹ Ìrékọjá pẹ̀lú àwọn àpọ́sítélì rẹ̀, ó wá fi Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa rọ́pò Ìrékọjá, ó sì ní kí wọ́n máa ṣe é lọ́dọọdún. Torí náà, ó ní kí Pétérù àti Jòhánù lọ ṣètò yàrá tí wọ́n máa lò. (Lk 22:​7-13; wo àwòrán iwájú ìwé.) Èyí jẹ́ ká rí i pé ó ṣe pàtàkì ká múra sílẹ̀ fún Ìrántí Ikú Kristi tá a máa ṣe ní March 27. Ó ṣeé ṣe kí Ìjọ ti ṣètò ohun ìṣàpẹẹrẹ, ẹni tó máa sọ àsọyé àtàwọn nǹkan míì. Àmọ́, kí ni ẹnì kọ̀ọ̀kan wa lè ṣe láti múra sílẹ̀ fún Ìrántí Ikú Kristi?

Túbọ̀ mọyì ikú Jésù. Ka àwọn ẹsẹ Bíbélì tá a máa ń kà nígbà Ìrántí Ikú Kristi, kó o sì ronú nípa wọn. A to àwọn ẹsẹ Bíbélì yẹn sínú Ṣíṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́. O tún lè wo Àfikún B12 nínú Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun kó o lè rí ìsọfúnni síwájú sí i. (Tún wo Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ ti oṣù April 2020.) Kẹ́ ẹ lè túbọ̀ mọyì ìràpadà nínú ìdílé yín, ẹ wo Watch Tower Publications Index tàbí Ìwé Ìwádìí fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, àwọn ìsọfúnni tẹ́ ẹ máa rí níbẹ̀ á ràn yín lọ́wọ́ nígbà ìjọsìn ìdílé yín.

Pe àwọn míì. Ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe láti pe ọ̀pọ̀ èèyàn. Ronú nípa àwọn tó o lè pè, irú bí àwọn ìpadàbẹ̀wò rẹ, àwọn tó ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tẹ́lẹ̀, àwọn ọ̀rẹ́ àtàwọn mọ̀lẹ́bí. Àwọn alàgbà máa wá bí wọ́n ṣe máa pe àwọn aláìṣiṣẹ́mọ́. Tó o bá fẹ́ mọ àkókò àti ibi tí wọ́n ti máa ṣe Ìrántí Ikú Kristi ládùúgbò ẹni kan tó o pè, wàá rí i lórí ìkànnì jw.org/yo, lọ sí abala NÍPA WA, kó o sì tẹ “Ìrántí.”

Àwọn nǹkan míì wo la lè ṣe láti múra sílẹ̀?