ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
Bí Ìgbàgbọ́ Ṣe Lè Jẹ́ Ká Nígboyà
Àwọn amí tó mú ìròyìn burúkú wá ò nígbàgbọ́ (Nọ 13:31-33; 14:11)
Torí pé àwọn amí mẹ́wàá yẹn ò nígbàgbọ́, wọ́n kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá àwọn tó kù (Nọ 14:1-4)
Àwọn amí tó jẹ́ onígboyà fi hàn pé àwọn ní ìgbàgbọ́ tó lágbára (Nọ 14:6-9; w06 10/1 17 ¶5-6)
Ṣáájú ìgbà yẹn, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti fojú ara wọn rí bí Jèhófà ṣe gbà wọ́n là, tó sì jà fún wọn. Ó yẹ kí àwọn nǹkan tí wọ́n rí yẹn mú kí ìgbàgbọ́ wọn lágbára, kí wọ́n sì gbà pé Jèhófà máa ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ṣẹ́gun àwọn ọmọ Kénáánì.