Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ | JẸ́ KÍ IṢẸ́ SÍSỌNI DI ỌMỌ Ẹ̀YÌN MÁA FÚN Ẹ LÁYỌ̀

Máa Lo Ìbéèrè

Máa Lo Ìbéèrè

“Ọlọ́run aláyọ̀” ni Jèhófà, ó sì fẹ́ ká gbádùn iṣẹ́ ìwàásù. (1Ti 1:11) Ayọ̀ wa á máa pọ̀ sí i tá a bá túbọ̀ ń já fáfá lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Tá a bá ń béèrè ìbéèrè, ó máa wu àwọn èèyàn láti gbọ́ ọ̀rọ̀ wa, á sì jẹ́ kó rọrùn fún wa láti bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò. Ìbéèrè tún máa ń jẹ́ káwọn èèyàn ronú jinlẹ̀. (Mt 22:​41-45) Tá a bá ń béèrè ìbéèrè, tá a sì ń tẹ́tí sílẹ̀ táwọn èèyàn bá ń dáhùn, ṣe ló dà bí ìgbà tá à ń sọ pé, ‘O ṣe pàtàkì sí mi.’ (Jem 1:19) Ìdáhùn ẹni náà máa jẹ́ ká mọ ohun tá a máa sọ.

Ẹ WO FÍDÍÒ NÁÀ JẸ́ KÍ IṢẸ́ SÍSỌNI DI ỌMỌ Ẹ̀YÌN MÁA FÚN Ẹ LÁYỌ̀​—TÚBỌ̀ JÁ FÁFÁ​—MÁA LO ÌBÉÈRÈ, KẸ́ Ẹ SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:

  • Àwọn ìwà tó dáa wo ni Jade ní?

  • Àwọn ìbéèrè wo ni Neeta bi Jade láti fa ojú ẹ̀ mọ́ra?

  • Àwọn ìbéèrè wo ni Neeta bi Jade tó mú kó túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ rẹ̀?

  • Àwọn ìbéèrè wo ni Neeta bi Jade tó mú kó ronú jinlẹ̀?