ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
Má Ṣe Máa Gbéra Ga, Má sì Dá Ara Rẹ Lójú Jù
Kórà di agbéraga, ó sì dá ara ẹ̀ lójú jù, torí náà kò fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú ètò tí Jèhófà ṣe (Nọ 16:1-3; w11 9/15 27 ¶12)
Ọmọ Léfì táwọn èèyàn bọ̀wọ̀ fún ni Kórà, ọ̀pọ̀ àǹfààní iṣẹ́ ìsìn ló sì ní (Nọ 16:8-10; w11 9/15 27 ¶11)
Kórà gba èròkerò láyè, ohun tó sì tẹ̀yìn ẹ̀ yọ ò dáa rárá (Nọ 16:32, 35)
A ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí àwọn àṣeyọrí tá a ṣe lẹ́nu iṣẹ́ Jèhófà mú ká di agbéraga tàbí ká máa dá ara wa lójú jù. Bá a bá ṣe ń pẹ́ sí i nínú òtítọ́ tàbí bí iṣẹ́ tá à ń bójú tó nínú ètò Ọlọ́run bá ṣe ń pọ̀ sí i, bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe yẹ ká túbọ̀ máa jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ sí i.