Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Àwọn Wo Lò Ń Bá Ṣọ̀rẹ́ Lórí Ìkànnì?

Àwọn Wo Lò Ń Bá Ṣọ̀rẹ́ Lórí Ìkànnì?

Ká tó lè pe ẹnì kan ní ọ̀rẹ́ wa, á jẹ́ pé ẹni náà sún mọ́ wa gan-an, a sì jọ nífẹ̀ẹ́ ara wa. Bí àpẹẹrẹ, Jónátánì àti Dáfídì di ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ lẹ́yìn tí Dáfídì pa Gòláyátì. (1Sa 18:1) Àwọn méjèèjì níwà tó dáa, ìyẹn ló sì mú kí wọ́n sún mọ́ra. Torí náà, ká tó lè di ọ̀rẹ́ ẹnì kan a gbọ́dọ̀ mọ ẹni náà dáadáa. Ká tó lè mọ ẹnì kan dáadáa, a gbọ́dọ̀ sapá láti sún mọ́ ọn, ìyẹn sì máa ń gba àkókò. Àmọ́ lórí ìkànnì àjọlò, àwọn èèyàn lè di “ọ̀rẹ́” ara wọn láàárín ìṣẹ́jú mélòó kan. Ó rọrùn fẹ́nì kan láti fi irú ẹni tó jẹ́ pa mọ́ lórí ìkànnì, torí pé ẹni náà ló máa pinnu ohun tó máa sọ àtohun tó fẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ nípa òun. Torí náà, o gbọ́dọ̀ fara balẹ̀ ronú dáadáa kó o tó di ọ̀rẹ́ ẹnì kan lórí ìkànnì. Tí ẹnì kan tó ò fi bẹ́ẹ̀ mọ̀ dáadáa bá sọ pé òun fẹ́ di ọ̀rẹ́ rẹ lórí ìkànnì àjọlò, má jẹ́ kẹ́rù bà ẹ́ láti kọ̀, kó o wá máa ronú pé tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀ ẹni náà máa bínú. Àwọn kan tiẹ̀ pinnu pé àwọn ò ní lo ìkànnì àjọlò rárá torí ewu tó wà níbẹ̀. Àmọ́ tó o bá pinnu pé wàá lò ó, kí ló yẹ kó o fi sọ́kàn?

Ẹ WO FÍDÍÒ NÁÀ MÁA FỌGBỌ́N LO ÌKÀNNÌ ÀJỌLÒ, KẸ́ Ẹ SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:

  • Kí ló yẹ kó o fi sọ́kàn kó o tó gbé àwòrán tàbí kọ ọ̀rọ̀ sórí ìkànnì àjọlò?

  • Kí nìdí tó fi yẹ kó o fọgbọ́n yan àwọn ọ̀rẹ́ rẹ lórí ìkànnì àjọlò?

  • Kí nìdí tí kò fi yẹ kó o lo àkókò tó pọ̀ jù nídìí ìkànnì àjọlò?​—Ef 5:15, 16