MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Ọ̀nà Mẹ́ta Tá A Lè Gbà Fi Hàn Pé A Gbára Lé Jèhófà
Dáfídì ṣẹ́gun Gòláyátì torí pé ó gbára lé Jèhófà. (1Sa 17:45) Ó máa ń wu Jèhófà láti fi agbára rẹ̀ hàn nítorí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀. (2Kr 16:9) Báwo la ṣe lè fi hàn pé a gbára lé Jèhófà dípò òye àti ìrírí tá a ní? Ẹ jẹ́ ká wo ọ̀nà mẹ́ta tá a lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀:
-
Máa gbàdúrà déédéé. Kò dìgbà tó o bá ṣàṣìṣe kó o tó gbàdúrà pé kí Jèhófà dárí jì ẹ́, ó yẹ kó o máa gbàdúrà pé kí Jèhófà fún ẹ lókun tó o bá ń kojú ìdẹwò, kó o má bàa dẹ́ṣẹ̀. (Mt 6:12, 13) Kì í ṣe ìgbà tá a bá ti ṣèpinnu tán nìkan ló yẹ ká gbàdúrà fún ìbùkún Jèhófà, àmọ́ ó tún yẹ ká máa gbàdúrà pé kí Jèhófà tọ́ wa sọ́nà kó sì fún wa lọ́gbọ́n tá a nílò ká tó ṣèpinnu.—Jem 1:5
-
Máa ka Bíbélì déédéé kó o sì máa dá kẹ́kọ̀ọ́. Máa ka Bíbélì lójoojúmọ́. (Sm 1:2) Ronú nípa àwọn àpẹẹrẹ tó wà nínú Bíbélì kó o sì fi àwọn ẹ̀kọ́ tó o bá kọ́ sílò. (Jem 1:23-25) Máa múra sílẹ̀ kó o tó lọ sóde ẹ̀rí, dípò kó o gbára lé ìrírí tó o ní. Yàtọ̀ síyẹn, tó o bá ń múra ìpàdé sílẹ̀, wà á túbọ̀ gbádùn ìpàdé náà.
-
Máa fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú ètò Ọlọ́run. Máa kíyè sí àwọn ìtọ́ni tó dé kẹ́yìn, kó o sì múra tán láti tẹ̀ lé wọn láìjáfara. (Nọ 9:17) Bákan náà, máa tẹ̀ lé àwọn ìtọ́ni táwọn alàgbà bá ń fún wa.—Heb 13:17
Ẹ WO FÍDÍÒ NÁÀ KÒ YẸ KÁ BẸ̀RÙ INÚNIBÍNI, KẸ́ Ẹ SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:
• Àwọn nǹkan wo ló ba àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa lẹ́rù?
• Àwọn nǹkan wo ló fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀?