Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Dáfídì kojú Gòláyátì

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

“Ogun Náà Jẹ́ Ti Jèhófà”

“Ogun Náà Jẹ́ Ti Jèhófà”

Ohun tí Dáfídì mọ̀ nípa Jèhófà àtàwọn ohun tó ti ṣe fún un ló jẹ́ kí ìgbàgbọ́ rẹ̀ lágbára (1Sa 17:36, 37; wp16.5 11 ¶2-3)

Dáfídì ò wo bí òun ṣe kéré lẹ́gbẹ̀ẹ́ Gòláyátì. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló wo bí Gòláyátì ṣe kéré lẹ́gbẹ̀ẹ́ Jèhófà (1Sa 17:45-47; wp16.5 11-12)

Jèhófà mú kí Dáfídì ṣẹ́gun ọ̀tá kan tó lágbára tó sì ń bani lẹ́rù (1Sa 17:48-50; wp16.5 12 ¶4; wo àwòrán iwájú ìwé)

Nígbà míì, a máa ń kojú àwọn ìṣòro tó le. Bí àpẹẹrẹ, a lè máa kojú inúnibíni tàbí ká máa sapá láti jáwọ́ nínú ìwà burúkú kan. Àwọn ìṣòro yìí lè dà bí òkè lójú wa, àmọ́ ká máa rántí pé àwọn ìṣòro náà kéré ní ìfiwéra pẹ̀lú agbára tí ò láàlà tí Jèhófà ní.​—Job 42:1, 2.