Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

TẸRA MỌ́ IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ | JẸ́ KÍ IṢẸ́ SÍSỌNI DI ỌMỌ Ẹ̀YÌN MÁA FÚN Ẹ LÁYỌ̀

Ran Àwọn Tó Ò Ń Kọ́ Lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Lọ́wọ́ Láti Jáwọ́ Nínú Ìwà Àìmọ́

Ran Àwọn Tó Ò Ń Kọ́ Lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Lọ́wọ́ Láti Jáwọ́ Nínú Ìwà Àìmọ́

Àwọn tó bá ń hùwà mímọ́ nìkan ló lè ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà. (1Pe 1:14-16) Báwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ṣe ń jáwọ́ nínú ìwàkiwà, ìlera wọn á túbọ̀ dáa, ìdílé wọn á láyọ̀, wọ́n á sì rówó gbọ́ bùkátà.

Ṣàlàyé àwọn ìlànà Jèhófà fún wọn, kó o sì jẹ́ kí wọ́n mọ ìdí tí Jèhófà fi fún wa láwọn ìlànà yẹn àtàwọn àǹfààní tá a máa rí tá a bá ń tẹ̀ lé wọn. Ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè máa ronú lọ́nà tó tọ́, bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́ ìwà wọn á yí pa dà. (Ef 4:22-24) Jẹ́ kó dá wọn lójú pé Jèhófà máa ràn wọ́n lọ́wọ́ láti jáwọ́ nínú ìwà àìmọ́ èyíkéyìí. (Flp 4:13) Jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé wọ́n lè bẹ Jèhófà taratara pé kó ràn wọ́n lọ́wọ́ nígbàkigbà tó bá ń ṣe wọ́n bíi pé kí wọ́n tún lọ́wọ́ nínú ìwà yẹn. Kọ́ wọn láti máa yẹra fáwọn ipò tó lè mú kó rọrùn fún wọn láti lọ́wọ́ nínú ìwà náà. Gbà wọ́n níyànjú pé kí wọ́n sapá láti ṣe ohun tó dáa nígbàkigbà tó bá ń wù wọ́n láti lọ́wọ́ nínú ìwà tí kò dáa. Tá a bá ń rí bí Jèhófà ṣe ń ran àwọn akẹ́kọ̀ọ́ wa lọ́wọ́ láti yí ìwà wọn pa dà, ó dájú pé inú wa máa dùn.

Ẹ WO FÍDÍÒ NÁÀ RAN ÀWỌN TÓ Ò Ń KỌ́ LẸ́KỌ̀Ọ́ BÍBÉLÌ LỌ́WỌ́ LÁTI JÁWỌ́ NÍNÚ ÌWÀ ÀÌMỌ́, KẸ́ Ẹ SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:

  • Báwo làwọn alàgbà àti Neeta ṣe fi hàn pé àwọn fọkàn tán Jade?

  • Báwo ni Neeta ṣe túbọ̀ ran Jade lọ́wọ́?

  • Kí ni Jade ṣe kí Jèhófà lè ràn án lọ́wọ́?