Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ

Ohun Tá A Lè Bá Àwọn Èèyàn Sọ

Ohun Tá A Lè Bá Àwọn Èèyàn Sọ

ÌKÉSÍNI SÍ ÌRÁNTÍ IKÚ KRISTI (March 11–April 4)

O lè sọ pé: “A fẹ́ pè yín síbi Ìrántí Ikú Kristi tá a máa ń ṣe lọ́dọọdún. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa wá síbi ìpàdé pàtàkì yìí kárí ayé.” Fún ẹni náà ní ìwé ìkésíni tàbí kó o fi ránṣẹ́ lórí ìkànnì. Kó o wá sọ pé: “Ìwé ìkésíni yìí máa jẹ́ kẹ́ ẹ mọ ibi tá a ti fẹ́ ṣe é ládùúgbò wa àti àkókò tó máa bẹ̀rẹ̀. A tún fẹ́ kẹ́ ẹ wá gbọ́ àkànṣe àsọyé kan ní ọ̀sẹ̀ tó ṣáájú Ìrántí Ikú Kristi náà.”

Tí Ẹni Náà Bá Nífẹ̀ẹ́ sí Ọ̀rọ̀ Rẹ: Jẹ́ kó wo fídíò náà Ìrántí Ikú Jésù [tàbí kó o fi ìlujá fídíò náà ránṣẹ́ sí i].

Ìbéèrè fún ìgbà míì: Kí nìdí tí Jésù fi kú?

NÍGBÀ ÀKỌ́KỌ́ (March 1-10, April 5-30)

Ìbéèrè: Ta ni Jésù?

Bíbélì: Mt 16:16

Ìbéèrè fún ìgbà míì: Kí nìdí tí Jésù fi kú?

ÌPADÀBẸ̀WÒ

Ìbéèrè: Kí nìdí tí Jésù fi kú?

Bíbélì: Mt 20:28

Ìbéèrè fún ìgbà míì: Báwo la ṣe lè fi hàn pé a mọyì bí Jésù ṣe kú fún wa?