Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ọbabìnrin Ṣébà ṣèbẹ̀wò sí ààfin Ọba Sólómọ́nì

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

Ọbabìnrin Ṣébà Mọyì Kéèyàn Jẹ́ Ọlọ́gbọ́n

Ọbabìnrin Ṣébà Mọyì Kéèyàn Jẹ́ Ọlọ́gbọ́n

Ọbabìnrin Ṣébà rin ìrìn àjò ọ̀nà tó jìn tó sì ń tánni lókun láti lọ rí Sólómọ́nì (2Kr 9:1, 2; w99 11/1 20 ¶4; w99 7/1 30 ¶4-5)

Nígbà tó rí ọgbọ́n àti ọrọ̀ Sólómọ́nì, ẹnu yà á gan-an (2Kr 9:3, 4; w99 7/1 30-31; wo àwòrán iwájú ìwé)

Ohun tó rí mú kó yin Jèhófà (2Kr 9:7, 8; it-2 990-991)

Ọbabìnrin Ṣébà mọyì kéèyàn ní ọgbọ́n. Ìyẹn ló jẹ́ kó yááfì ọ̀pọ̀ nǹkan kó lè ní i. 

BI ARA RẸ PÉ, ‘Ṣé mo ṣe tán láti wá ọgbọ́n bí ìgbà téèyàn ń wá àwọn ìṣúra tó fara sin?’​—Owe 2:1-6.