MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Bá A Ṣe Lè Lo Àwọn Fídíò Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì
Ètò Ọlọ́run ti ṣe àwọn fídíò mẹ́rin tó wà fún ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tá a lè lò lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Kí nìdí tá a fi ṣe ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn?
-
Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kó O Kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?—Èyí tó Gùn. A ṣe fídíò yìí láti jẹ́ kí àwọn èèyàn nífẹ̀ẹ́ Bíbélì láìka ẹ̀sìn tí wọ́n ń ṣe sí. Àwọn tó bá wo fídíò náà a rí i pé inú Bíbélì làwọn ti lè rí ìdáhùn sáwọn ìbéèrè tó ṣe pàtàkì nígbèésí ayé. Bákan náà, ó tún sọ ohun tí wọ́n lè ṣe tí wọ́n bá fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.
-
Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kó O Kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì? (èyí tó kúrú) Ohun tó wà nínú fídíò náà jọ ti èyí tó gùn, àmọ́ ọ̀rọ̀ inú ẹ̀ ṣe ṣókí. Ó máa dùn ń lò láwọn ìpínlẹ̀ táwọn èèyàn kì í fi bẹ́ẹ̀ ráyè fún ìjíròrò.
-
Báwo La Ṣe Máa Ń Ṣe Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì? Fídíò yìí máa jẹ́ kó túbọ̀ wu àwọn èèyàn láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tá a máa ń ṣe lọ́fẹ̀ẹ́, kí wọ́n sì rí ìdáhùn sáwọn ìbéèrè wọn. Bákan náà, ó tún sọ ohun tí wọ́n lè ṣe tí wọ́n bá fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.
-
Ohun Tó O Máa Gbádùn Nínú Ẹ̀kọ́ Bíbélì Rẹ. A máa ń fi fídíò yìí han àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ojú ìwé kejì nínú ìwé Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì ni fídíò náà wà, a ṣì lè fi han àwọn èèyàn tá a bá ń jíròrò ìwé Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìbẹ̀rẹ̀ Ẹ̀kọ́ Bíbélì. Fídíò náà sọ̀rọ̀ nípa ohun tí akẹ́kọ̀ọ́ máa gbádùn àti ohun tó wà nínú ìwé náà.
Òótọ́ ni pé ìdí tá a fi ṣe fídíò kọ̀ọ̀kan la jíròrò lókè yìí, àmọ́ a ṣì lè fi han àwọn èèyàn tàbí ká fi ránṣẹ́ sí wọn nígbàkigbà tá a bá rí i pé ó yẹ ká ṣe bẹ́ẹ̀. A rọ àwọn akéde pé kí wọ́n mọ ohun tó wà nínú ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn fídíò yìí dáadáa, kí wọ́n sì máa lò wọ́n lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù.