Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Máa Ṣe Àwọn Ìpinnu Tó Fi Hàn Pé O Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà

Máa Ṣe Àwọn Ìpinnu Tó Fi Hàn Pé O Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà

Ojoojúmọ́ la máa ń bára wa láwọn ipò tó gba pé ká ṣèpinnu. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló jẹ́ pé bí nǹkan bá ṣe rí lára wọn tàbí ohun tí ọ̀pọ̀ èèyàn ń ṣe ni wọ́n máa ń gbé àwọn ìpinnu wọn ka. (Ẹk 23:2; Owe 28:26) Àmọ́ àwọn tó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà “máa kíyè sí i” ní ti pé wọ́n máa ń lo àwọn ìlànà Bíbélì tí wọ́n bá fẹ́ ṣèpinnu.​—Owe 3:5, 6.

Kọ àwọn ipò tí àwọn ẹsẹ Bíbélì yìí ti lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti ṣe àwọn ìpinnu tó dáa.

JẸ́ KÍ ÀWỌN ARÁ WO FÍDÍÒ TẸ̀ LÉ ÀPẸẸRẸ ÀWỌN TÓ NÍ ÌGBÀGBỌ́, KÌ Í ṢE ÀWỌN TÍ KÒ NÍGBÀGBỌ́—TẸ̀ LÉ MÓSÈ, MÁ TẸ̀ LÉ FÁRÁÒ, KẸ́ Ẹ SÌ DÁHÙN ÌBÉÈRÈ TÓ TẸ̀ LÉ E YÌÍ:

Báwo ni àpẹẹrẹ kan nínú Bíbélì ṣe ran arákùnrin yìí lọ́wọ́ láti ṣe ìpinnu tó tọ́?