March 20-26
2 KÍRÓNÍKÀ 1-4
Orin 41 àti Àdúrà
Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
“Ọba Sólómọ́nì Ṣe Ìpinnu Tí Ò Mọ́gbọ́n Dání”: (10 min.)
Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì: (10 min.)
2Kr 1:11, 12—Kí ni ẹsẹ Bíbélì yìí kọ́ wa nípa àdúrà wa? (w05 12/1 19 ¶6)
Àwọn ẹ̀kọ́ iyebíye wo lo tún rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí nípa Jèhófà, iṣẹ́ ìwàásù tàbí àwọn nǹkan míì?
Bíbélì Kíkà: (4 min.) 2Kr 4:7-22 (th ẹ̀kọ́ 10)
TẸRA MỌ́ IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ
Ìkésíni sí Ìrántí Ikú Kristi: (3 min.) Pe ẹni tẹ́ ẹ jọ ń ṣiṣẹ́, ọmọ iléèwé rẹ tàbí mọ̀lẹ́bí rẹ wá sí Ìrántí Ikú Kristi. (th ẹ̀kọ́ 2)
Ìpadàbẹ̀wò: (4 min.) Pa dà lọ sọ́dọ̀ ẹnì kan tó nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ rẹ, tó sì gba ìwé ìkésíni. Ṣàlàyé bá a ṣe máa ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́fẹ̀ẹ́, kó o sì fún ẹni náà ní ìwé Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìbẹ̀rẹ̀ Ẹ̀kọ́ Bíbélì. Ṣe bíi pé ẹ wo fídíò Báwo La Ṣe Máa Ń Ṣe Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì? kẹ́ ẹ sì jíròrò rẹ̀ (àmọ́ ẹ má ṣe wò ó) (th ẹ̀kọ́ 17)
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì: (5 min.) lff ẹ̀kọ́ 09 kókó 5 (th ẹ̀kọ́ 9)
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Ṣé Wàá Múra Ọkàn Ẹ Sílẹ̀ fún Ọjọ́ Tó Ṣe Pàtàkì Jù Lọ Nínú Ọdún?: (15 min.) Àsọyé àti fídíò. Alábòójútó iṣẹ́ ìsìn ni kó bójú tó apá yìí. Jẹ́ kí ìjọ mọ ibi tẹ́ ẹ pín ìwé ìkésíni dé. Fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu àwọn tó ní ìrírí tó lárinrin bẹ́ ẹ ṣe ń pín ìwé náà. Gba àwọn ará níyànjú pé kí wọ́n wo ìtòlẹ́sẹẹsẹ Bíbélì kíkà tó wà fún Ìrántí Ikú Kristi tó wà lójú ìwé 8 àti 9, kí wọ́n sì múra ọkàn wọn sílẹ̀ fún Ìrántí Ikú Kristi. (Ẹsr 7:10) Sọ̀rọ̀ nípa bó ṣe yẹ ká kí àwọn tá a pè káàbọ̀ lálẹ́ ọjọ́ Ìrántí Ikú Kristi. (Ro 15:7; mwb16.03 2) Ẹ wo fídíò náà Bó O Ṣe Lè Ṣe Búrẹ́dì Ìrántí Ikú Kristi.
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: (30 min.) lff ẹ̀kọ́ 41 kókó 1-4
Ọ̀rọ̀ Ìparí (3 min.)
Orin 135 àti Àdúrà