ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
Ọba Sólómọ́nì Ṣe Ìpinnu Tí Ò Mọ́gbọ́n Dání
[Jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Kíróníkà Kejì.]
Sólómọ́nì ń kó kẹ̀kẹ́ ẹṣin àti ẹṣin jọ fún ara rẹ̀ láti Íjíbítì (Di 17:15, 16; 2Kr 1:14, 17)
Sólómọ́nì nílò ọ̀pọ̀ èèyàn àti ìlú láti bójú tó àwọn ẹṣin àtàwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin ogun rẹ̀ (2Kr 1:14; it-1 174 ¶5; 427)
Nǹkan lọ dáadáa fáwọn èèyàn nígbà tí Sólómọ́nì kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso. Àmọ́ nígbà tó ya, ó mú kí nǹkan nira fún wọn. Nígbà tí Rèhóbóámù ọmọ rẹ̀ di ọba, ó túbọ̀ mú kí nǹkan nira fáwọn èèyàn náà, ìyẹn sì mú kí wọ́n kẹ̀yìn sí i. (2Kr 10:3, 4, 14, 16) Gbogbo ìpinnu tá a bá ṣe ló máa ní àbájáde.—Ga 6:7.