Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

“Ọkàn Mi Á Máa Wà Níbẹ̀ Nígbà Gbogbo”

“Ọkàn Mi Á Máa Wà Níbẹ̀ Nígbà Gbogbo”

Jèhófà yan tẹ́ńpìlì náà fún ara ẹ̀ (2Kr 7:11, 12)

Jèhófà sọ pé ọkàn òun á máa wà níbẹ̀ nígbà gbogbo, ìyẹn ni pé á máa kíyè sí àwọn nǹkan tó bá ń ṣẹlẹ̀ níbẹ̀ nítorí orúkọ mímọ́ rẹ̀ (2Kr 7:16; w02 11/15 5 ¶1)

Tí àwọn èèyàn náà ò bá fi “gbogbo ọkàn wọn” rìn níwájú Jèhófà mọ́, ó máa jẹ́ kí wọ́n pa tẹ́ńpìlì náà run (2Kr 6:14; 7:19-21; it-2 1077-1078)

Lásìkò tí wọ́n ń ya tẹ́ńpìlì náà sí mímọ́, àwọn èèyàn náà rò pé àwọn á máa fi gbogbo ọkàn wọn ṣe ìjọsìn Jèhófà. Àmọ́, ó bani nínú jẹ́ pé kò pẹ́ tí ìtara wọn fún ìjọsìn Jèhófà fi bẹ̀rẹ̀ sí í dín kù.

BI ARA RẸ PÉ, ‘Báwo ni mo ṣe lè fi hàn pé mo ka ìjọsìn Jèhófà sí pàtàkì?’