MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
“Dáàbò Bo Ọkàn Rẹ”
Jèhófà mí sí Sólómọ́nì láti sọ pé: “Ju gbogbo ohun mìíràn tí ò ń dáàbò bò, dáàbò bo ọkàn rẹ.” (Owe 4:23) Ó bani nínú jẹ́ pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ò fi “gbogbo ọkàn wọn” bá Jèhófà Ọlọ́run wọn rìn. (2Kr 6:14) Kódà àwọn ìyàwó àjèjì tí Ọba Sólómọ́nì fẹ́ mú kí ọkàn rẹ̀ fà sí àwọn ọlọ́run míì. (1Ọb 11:4) Báwo lo ṣe lè dáàbò bo ọkàn rẹ? Ohun tá a jíròrò nìyẹn nínú Ilé Ìṣọ́ January 2019 ojú ìwé 14 sí 19.
Ẹ WO FÍDÍÒ NÁÀ ÀWỌN Ẹ̀KỌ́ LÁTINÚ ILÉ ÌṢỌ́—DÁÀBÒ BO ỌKÀN RẸ, KẸ́ Ẹ SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:
Kí làwọn ohun tó fẹ́ ba ìgbàgbọ́ àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin yìí jẹ́, báwo sì ni àpilẹ̀kọ tó wà fún ìkẹ́kọ̀ọ́ yìí ṣe ràn wọ́n lọ́wọ́ láti dáàbò bo ọkàn wọn?
-
Brent àti Lauren
-
Umjay
-
Happy Layou
Báwo ni àpilẹ̀kọ náà ṣe ràn ẹ́ lọ́wọ́?