Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Bá A Ṣe Lè Ṣèrànwọ́ Tí Àjálù Bá Ṣẹlẹ̀

Bá A Ṣe Lè Ṣèrànwọ́ Tí Àjálù Bá Ṣẹlẹ̀

Lónìí, àwọn àjálù tó ń ṣẹlẹ̀ túbọ̀ ń pọ̀ sí i. Tí àjálù bá ṣẹlẹ̀, ó yẹ kí ọ̀nà tá a máa gbà ṣètò ìrànwọ́ wà létòlétò kó sì gbéṣẹ́. Kí èyí lè ṣeé ṣe, Ìgbìmọ̀ Olùdarí ti ṣètò pé kí Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Ọ̀rọ̀ Àjálù wà ní gbogbo ẹ̀ka ọ́fíìsì.

Tí àwọn arákùnrin tó wà ní ẹ̀ka yìí bá gbọ́ pé àjálù ṣẹlẹ̀ níbì kan, ojú ẹsẹ̀ ni wọ́n á kàn sí àwọn alàgbà tó wà lágbègbè náà kí wọ́n lè mọ ohun táwọn ará nílò. Tí àjálù náà bá kọjá ohun táwọn ará lè bójú tó fúnra wọn, ẹ̀ka ọ́fíìsì máa yan àwọn arákùnrin tó kúnjú ìwọ̀n láti bójú tó ètò ìrànwọ́ náà. Àwọn arákùnrin yìí lè béèrè fún àwọn tó máa yọ̀ǹda ara wọn, tàbí kí wọ́n béèrè àwọn ohun èlò kan ní pàtó, wọ́n sì lè ra àwọn ohun tí wọ́n nílò ládùúgbò, kí wọ́n sì pín in fáwọn ará.

Ọ̀pọ̀ àǹfààní la máa rí tá a bá ń tẹ̀ lé ètò tí ẹ̀ka ọ́fíìsì ṣe yìí. Torí, tá ò bá ṣe bẹ́ẹ̀ tí kálukú sì ń ṣètò tara ẹ̀, iṣẹ́ náà kò ní wà létòlétò, a ò ní lè ṣọ́wó ná, a ò sì ní lè lo àwọn nǹkan tá a ní bó ṣe yẹ. Yàtọ̀ síyẹn, iṣẹ́ náà tún máa gba ọ̀pọ̀ àkókò.

Àwọn arákùnrin tí ẹ̀ka ọ́fíìsì yan ló máa pinnu iye tá a máa ná àti iye olùyọ̀ǹda ara ẹni tá a máa nílò fún ètò ìrànwọ́ náà. Wọ́n tún lè kàn sí àwọn aṣojú ìjọba tó lè ràn wọ́n lọ́wọ́ kí iṣẹ́ ìrànwọ́ náà lè yá. Torí náà, ẹ jọ̀ọ́, kí ẹnikẹ́ni má ṣe ní káwọn ará dá owó kankan, ẹ má sì fi ohun èlò kankan ránṣẹ́, tàbí kẹ́ ẹ rìnrìn àjò lọ sí ibi tí àjálù náà ti ṣẹlẹ̀, àyàfi tí ẹ̀ka ọ́fíìsì bá sọ pé kẹ́ ẹ ṣe bẹ́ẹ̀.

Lóòótọ́, tí àjálù bá ṣẹlẹ̀, ó máa ń wù wá ká ran àwọn ará wa lọ́wọ́. (Heb 13:16) Ìdí sì ni pe a nífẹ̀ẹ́ wọn gan-an! Àmọ́ kí la lè ṣe tí àjálù bá ṣẹlẹ̀ sí wọn? Ohun tó ṣe pàtàkì jù ni pé, ká gbàdúrà fáwọn tí àjálù náà ṣẹlẹ̀ sí àtàwọn tó ń ṣètò ìrànwọ́ fún wọn. A tún lè fowó ṣètìlẹyìn fún iṣẹ́ kárí ayé. Lábẹ́ ìtọ́sọ́nà Ìgbìmọ̀ Olùdarí, ẹ̀ka ọ́fíìsì máa pinnu ọ̀nà tó dáa jù tá a máa gbà ná àwọn owó tẹ́ ẹ fi ń ṣètọrẹ. Tó o bá fẹ́ yọ̀ǹda ara ẹ, kọ ọ̀rọ̀ kún fọ́ọ̀mù Local Design/Construction Volunteer Application (DC-50).

Ẹ WO FÍDÍÒ NÁÀ OMÍYALÉ BA Ọ̀PỌ̀ NǸKAN JẸ́ NÍ BRAZIL, KẸ́ Ẹ SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:

Kí ló wú ẹ lórí nípa ètò ìrànwọ́ tó wáyé nígbà tí àkúnya omi ṣẹlẹ̀ ní Brazil lọ́dún 2020?