ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
Bí Wọ́n Ṣe Ń Jọ́sìn Nínú Tẹ́ńpìlì Túbọ̀ Wà Létòlétò
Ọba Dáfídì ṣètò àwọn ọmọ Léfì àtàwọn àlùfáà kí wọ́n lè máa ṣiṣẹ́ ìsìn nínú tẹ́ńpìlì (1Kr 23:6, 27, 28; 24:1, 3; it-2 241, 686)
Wọ́n yan àwọn ọ̀jáfáfá àtàwọn akẹ́kọ̀ọ́ kí wọ́n lè máa kọrin ìyìn sí Jèhófà (1Kr 25:1, 8; it-2 451-452)
Wọ́n yan àwọn ọmọ Léfì kan láti máa bójú tó àwọn ibi ìṣúra, àwọn míì jẹ́ aṣọ́bodè, àwọn míì sì ń ṣe àwọn iṣẹ́ pàtàkì míì (1Kr 26:16-20; it-1 898)
Bá a ṣe wà létòlétò fi hàn pé Jèhófà jẹ́ Ọlọ́run ètò.—1Kọ 14:33.
ṢE ÀṢÀRÒ: Báwo ni ìjọ Kristẹni òde òní ṣe ń jọ́sìn Jèhófà létòlétò?