Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

April 15-21

SÁÀMÙ 29-31

April 15-21

Orin 108 àti Àdúrà | Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

1. Jèhófà Máa Ń Bá Wa Wí Torí Pé Ó Nífẹ̀ẹ́ Wa

(10 min.)

Jèhófà fi ojú rẹ̀ pa mọ́ nígbà tí Dáfídì ṣàìgbọràn (Sm 30:7; it-1 802 ¶3)

Dáfídì ronú pìwà dà, ó sì bẹ Jèhófà pé kó ṣojú rere sí òun (Sm 30:8)

Jèhófà ò bínú lọ títí sí Dáfídì (Sm 30:5; w07 3/1 19 ¶1)

Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ohun tó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tí Dáfídì ka àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ló wà nínú Sáàmù 30.—2Sa 24:25.

RONÚ LÓRÍ ÌBÉÈRÈ YÌÍ: Àǹfààní wo ni ìbáwí máa ṣe ẹni tí wọ́n yọ lẹ́gbẹ́, àwọn nǹkan wo ló sì máa ṣe táá fi hàn pé ó ronú pìwà dà?—w21.10 6 ¶18.

2. Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì

(10 min.)

  • Sm 31:23—Báwo ni Jèhófà ṣe máa ń san èrè tó kún rẹ́rẹ́ fún àwọn agbéraga? (w06 5/15 19 ¶13)

  • Àwọn ẹ̀kọ́ iyebíye wo lo rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí tí wàá fẹ́ sọ?

3. Bíbélì Kíkà

TẸRA MỌ́ IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ

4. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa

(1 min.) ÌWÀÁSÙ NÍBI TÍ ÈRÒ PỌ̀ SÍ. Wàásù ní ṣókí fún ẹnì kan tí ọwọ́ ẹ̀ dí. (lmd ẹ̀kọ́ 5 kókó 3)

5. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa

(3 min.) ÌWÀÁSÙ ÀÌJẸ́-BÍ-ÀṢÀ. Fi fídíò àwọn ọmọdé han ìyá kan, kó o sì ṣàlàyé bó ṣe lè rí àwọn fídíò míì. (lmd ẹ̀kọ́ 3 kókó 3)

6. Pa Dà Lọ

(3 min.) ÌWÀÁSÙ NÍBI TÍ ÈRÒ PỌ̀ SÍ. O ti fi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ ẹni náà nígbà kan rí, àmọ́ kò gbà. Gbìyànjú láti tún fi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ̀ ọ́. (lmd ẹ̀kọ́ 8 kókó 3)

7. Sọ Àwọn Èèyàn Di Ọmọ Ẹ̀yìn

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Orin 45

8. Ìdí Tá A Fi Gbà Gbọ́ Pé . . . Ọlọ́run Nífẹ̀ẹ́ Wa

(7 min.) Ìjíròrò. Jẹ́ kí àwọn ará wo FÍDÍÒ náà. Lẹ́yìn náà, béèrè pé:

Kí ni ìrírí arákùnrin yìí jẹ́ ká mọ̀ nípa bí Ọlọ́run ṣe nífẹ̀ẹ́ wa tó?

9. Ìròyìn Ẹ̀ka Tó Ń Yàwòrán Ilé Tó sì Ń Kọ́ Ọ ti Ọdún 2024

(8 min.) Àsọyé. Jẹ́ kí àwọn ará wo FÍDÍÒ náà.

10. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ

(30 min.) bt orí 8 ¶13-21

Ọ̀rọ̀ Ìparí (3 min.) | Orin 99 àti Àdúrà