April 22-28
SÁÀMÙ 32-33
Orin 103 àti Àdúrà | Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)
1. Ìdí Tó Fi Yẹ Ká Jẹ́wọ́ Ẹ̀ṣẹ̀ Tó Wúwo
(10 min.)
Ọkàn Dáfídì ò balẹ̀ nígbà tó ń gbìyànjú láti bo ẹ̀ṣẹ̀ tó ṣeé ṣe kó dá pẹ̀lú Bátí-ṣébà mọ́lẹ̀ (Sm 32:3, 4; w93 3/15 9 ¶7)
Dáfídì jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, Jèhófà sì dárí jì í (Sm 32:5; cl 262 ¶8)
Ara tu Dáfídì nígbà tí Jèhófà dárí jì í (Sm 32:1; w01 6/1 30 ¶1)
Tá a bá dá ẹ̀ṣẹ̀ tó wúwo, ó yẹ ká jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wa fún Jèhófà ká sì bẹ̀ ẹ́ pé kó dárí jì wá. Ó tún yẹ ká sọ fún àwọn alàgbà kí wọ́n lè ràn wá lọ́wọ́ láti pa dà ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà. (Jem 5:14-16) Èyí á jẹ́ ká lè rí ìtura gbà látọ̀dọ̀ Jèhófà.—Iṣe 3:19.
2. Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
(10 min.)
Sm 33:6—Kí ni “èémí” ẹnu Jèhófà? (w06 5/15 20 ¶1)
Àwọn ẹ̀kọ́ iyebíye wo lo rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí tí wàá fẹ́ sọ?
3. Bíbélì Kíkà
(4 min.) Sm 33:1-22 (th ẹ̀kọ́ 11)
4. Jẹ́ Onírẹ̀lẹ̀—Ohun Tí Pọ́ọ̀lù Ṣe
(7 min.) Ìjíròrò. Jẹ́ kí àwọn ará wo FÍDÍÒ náà, lẹ́yìn náà, ẹ jíròrò lmd ẹ̀kọ́ 4 kókó 1-2.
5. Jẹ́ Onírẹ̀lẹ̀—Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Pọ́ọ̀lù
(8 min.) Ìjíròrò tó dá lórí lmd ẹ̀kọ́ 4 kókó 3-5 àti “Tún Wo.”
Orin 74
6. Ohun Tó Ń Fẹ́ Àbójútó Nínú Ìjọ
(15 min.)
7. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ
(30 min.) bt orí 8 ¶22-24, àpótí ojú ìwé 67