April 29–May 5
SÁÀMÙ 34-35
Orin 10 àti Àdúrà | Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)
1. “Máa Yin Jèhófà ní Gbogbo Ìgbà”
(10 min.)
Gbogbo ìgbà ni Dáfídì máa ń yin Jèhófà kódà ó máa ń ṣe bẹ́ẹ̀ láwọn àkókò tó ní ìṣòro (Sm 34:1; w07 3/1 22 ¶11)
Jèhófà ni Dáfídì fi ń yangàn dípò kó máa gbé ara ẹ̀ ga (Sm 34:2-4; w07 3/1 22 ¶13)
Àwọn ọ̀rọ̀ ìyìn tí Dáfídì ń sọ fi àwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ lọ́kàn balẹ̀ (Sm 34:5; w07 3/1 23 ¶15)
Lẹ́yìn tí Jèhófà gbà á sílẹ̀ lọ́wọ́ Ábímélékì, àwọn ọgọ́rùn-ún mẹ́rin (400) ọkùnrin tí nǹkan nira fún lábẹ́ àkóso Sọ́ọ̀lù dara pọ̀ mọ́ Dáfídì nínú aginjù. (1Sa 22:1, 2) Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ àwọn ọkùnrin yìí ni Dáfídì ní lọ́kàn nígbà tó ń kọ sáàmù yìí.—Sm 34, àkọlé.
BI ARA RẸ PÉ, ‘Báwo ni mo ṣe lè yin Jèhófà tí mo bá ń bá ẹnì kan sọ̀rọ̀ ní ìpàdé ìjọ tó ń bọ̀?’
2. Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
(10 min.)
-
Sm 35:19—Kí ni Dáfídì ní lọ́kàn nígbà tó bẹ Jèhófà pé kó má ṣe jẹ́ káwọn tó kórìíra òun wo òun tìkà-tẹ̀gbin? (w06 5/15 20 ¶2)
-
Àwọn ẹ̀kọ́ iyebíye wo lo rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí tí wàá fẹ́ sọ?
3. Bíbélì Kíkà
(4 min.) Sm 34:1-22 (th ẹ̀kọ́ 5)
4. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa
(2 min.) ÌWÀÁSÙ ÀÌJẸ́-BÍ-ÀṢÀ. O ò ráyè wàásù títí ìjíròrò náà fi parí. (lmd ẹ̀kọ́ 1 kókó 4)
5. Pa Dà Lọ
(4 min.) ÌWÀÁSÙ ÀÌJẸ́-BÍ-ÀṢÀ. (lmd ẹ̀kọ́ 2 kókó 4)
6. Ṣàlàyé Ohun Tó O Gbà Gbọ́
(5 min.) Àṣefihàn. ijwfq 59—Àkòrí: Báwo Ni Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ṣe Máa Ń Mọ̀ Bóyá Inú Ọlọ́run Dùn sí Ayẹyẹ Kan Tàbí Kò Dùn? (th ẹ̀kọ́ 17)
Orin 59
7. Ọ̀nà Mẹ́ta Tó O Lè Gbà Yin Jèhófà Nípàdé
(15 min.) Ìjíròrò.
A máa ń láǹfààní láti yin Jèhófà láwọn ìpàdé wa. Ẹ jẹ́ ká wo ọ̀nà mẹ́ta tá a lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀.
Máa bá àwọn ará sọ̀rọ̀: Máa sọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun rere tí Jèhófà ń ṣe tó o bá ń bá àwọn ará sọ̀rọ̀. (Sm 145:1, 7) Ṣé ohun kan wà tó o gbọ́ tàbí tó o kà tó ṣe ẹ́ láǹfààní? Ṣé o láwọn ìrírí tó gbádùn mọ́ni lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù? Ṣé ohun kan wà tẹ́nì kan sọ tàbí tó ṣe tó fún ẹ níṣìírí? Ṣé àwọn nǹkan kan wà tó o kíyè sí nínú ohun tí Jèhófà dá tó wú ẹ lórí? Gbogbo àwọn nǹkan yìí jẹ́ ẹ̀bùn látọ̀dọ̀ Jèhófà. (Jem 1:17) Tètè dé kó o lè ráyè bá àwọn ará sọ̀rọ̀.
Máa dáhùn: Gbìyànjú láti máa dáhùn ó kéré tán lẹ́ẹ̀kan nípàdé. (Sm 26:12) O lè dáhùn ìbéèrè kan ní tààràtà tàbí kó o sọ̀rọ̀ nípa kókó míì nínú ìpínrọ̀ náà. O sì lè ṣàlàyé ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan, àwòrán kan tàbí kó o sọ bá a ṣe lè fi kókó inú ìpínrọ̀ náà sílò. Múra ọ̀pọ̀ ìdáhùn sílẹ̀ torí pé ó ṣeé ṣe káwọn míì nawọ́ láwọn ìpínrọ̀ tó o múra. Má ṣe jẹ́ kí ìdáhùn rẹ gùn jù, kó má ju ààbọ̀ ìṣẹ́jú tàbí kó má tiẹ̀ tó bẹ́ẹ̀. Ìyẹn á jẹ́ káwọn tó kù náà láǹfààní láti “rú ẹbọ ìyìn sí Ọlọ́run.”—Heb 13:15.
Máa kọrin: Máa fìtara kọrin nípàdé. (Sm 147:1) Ó lè má jẹ́ gbogbo ìpàdé lo ti máa láǹfààní láti dáhùn, pàápàá tó bá jẹ́ pé àwọn akéde pọ̀ níjọ yín, àmọ́ kò sígbà tó ò lè kọrin nípàdé. Tó bá tiẹ̀ ń ṣe ẹ́ bíi pé ohùn ẹ ò dáa tó, inú Jèhófà máa dùn tó o bá sapá láti kọrin láìka bí ohùn ẹ ṣe rí sí. (2Kọ 8:12) O tiẹ̀ lè fi àwọn orin tẹ́ ẹ máa kọ dánra wò nígbà tó o bá ń múra ìpàdé sílẹ̀.
Jẹ́ kí àwọn ará wo FÍDÍÒ Ìtàn Wa—Ẹ̀bùn Ọlọ́run ni Orin Kíkọ, Apá Kìíní. Lẹ́yìn náà, béèrè pé:
Àwọn nǹkan wo ló fi hàn pé ọwọ́ pàtàkì la fi mú kíkọ orin ìyìn sí Jèhófà láwọn ọdún tó ti kọjá sẹ́yìn?
8. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ
(30 min.) bt orí 9 ¶1-7, ọ̀rọ̀ ìbẹ̀rẹ̀ apá 3 àti àpótí ojú ìwé 70