March 18-24
SÁÀMÙ 19-21
Orin 6 àti Àdúrà | Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)
1. “Àwọn Ọ̀run Ń Polongo Ògo Ọlọ́run”
(10 min.)
Àwọn ohun tí Jèhófà dá ń kéde ògo rẹ̀ (Sm 19:1; w04 1/1 8 ¶1-2)
Oòrùn jẹ́ ọ̀kan lára àwọn iṣẹ́ Jèhófà tó jẹ́ àgbàyanu (Sm 19:4-6; w04 6/1 11 ¶8-10)
Ó yẹ ká máa kẹ́kọ̀ọ́ lára àwọn ohun tí Jèhófà dá (Mt 6:28; g95 11/8 7 ¶3)
OHUN TẸ́ Ẹ LÈ ṢE NÍGBÀ ÌJỌSÌN ÌDÍLÉ: Ẹ kíyè sí àwọn ohun tí Jèhófà dá, kẹ́ ẹ sì jíròrò ohun tí wọ́n kọ́ yín nípa Jèhófà.
2. Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
(10 min.)
Sm 19:7-9—Irú ewì wo ló wà nínú àwọn ẹsẹ yìí? (it-1 1073)
Àwọn ẹ̀kọ́ iyebíye wo lo rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí tí wàá fẹ́ sọ?
3. Bíbélì Kíkà
(4 min.) Sm 19:1-14 (th ẹ̀kọ́ 11)
4. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa
(3 min.) ÌWÀÁSÙ NÍBI TÍ ÈRÒ PỌ̀ SÍ. Fún ẹnì kan ní ìwé tá a fi ń pe èèyàn sí Ìrántí Ikú Kristi, wo ibi tí wọ́n ti máa ṣe Ìrántí Ikú Kristi lágbègbè ẹni náà lórí jw.org. (lmd ẹ̀kọ́ 2 kókó 3)
5. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa
(4 min.) ÌWÀÁSÙ ÀÌJẸ́-BÍ-ÀṢÀ. Ẹnì kan sọ fún ẹ pé òun rí ìwé tá a fi ń pe àwọn èèyàn lẹ́nu ọ̀nà òun ló jẹ́ kóun wá sí Ìrántí Ikú Kristi. Kí ẹni náà tọ̀yàyàtọ̀yàyà, kó o sì ṣètò bó o ṣe máa dáhùn àwọn ìbéèrè ẹ̀. (lmd ẹ̀kọ́ 3 kókó 4)
6. Ṣàlàyé Ohun Tó O Gbà Gbọ́
(5 min.) Àsọyé. ijwfq 45—Àkòrí: Kí Nìdí Tí Ọ̀nà Tí Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà Gbà Ń Ṣe Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa Fi Yàtọ̀ sí Ti Àwọn Ẹlẹ́sìn Tó Kù? (th ẹ̀kọ́ 6)
Orin 141
7. Jẹ́ Kí Àwọn Ohun Tí Jèhófà Dá Mú Kí Ìgbàgbọ́ Rẹ Lágbára Sí I
(15 min.) Ìjíròrò. Jẹ́ kí àwọn ará wo FÍDÍÒ náà. Lẹ́yìn náà, béèrè pé:
Àwọn nǹkan wo lo rí nínú fídíò yìí tó mú kí ìgbàgbọ́ rẹ nínú Ẹlẹ́dàá lágbára sí i?
8. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ
(30 min.) bt orí 7 ¶9-13, àpótí ojú ìwé 56