Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

March 4-10

SÁÀMÙ 16-17

March 4-10

Orin 111 àti Àdúrà | Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

1. “Jèhófà, Orísun Oore Mi”

(10 min.)

Tá a bá ń bá àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà ṣọ̀rẹ́, inú wa á máa dùn (Sm 16:2, 3; w18.12 26 ¶11)

Tá a bá ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà, ọkàn wa máa balẹ̀ (Sm 16:5, 6; w14 2/15 29 ¶4)

Bí Jèhófà ṣe ń dáàbò bò wá nípa tẹ̀mí máa ń jẹ́ kó dá wa lójú pé mìmì kan ò lè mì wá (Sm 16:8, 9; w08 2/15 3 ¶2-3)

Bíi ti Dáfídì, tá a bá fi ìjọsìn Jèhófà, Ẹni tó jẹ́ Orísun oore wa ṣáájú láyé wa, ó dájú pé ìgbésí ayé wa máa nítumọ̀.

BI ARA RẸ PÉ, ‘Àwọn nǹkan wo ló jẹ́ kí n gbà pé ìgbésí ayé mi ti sàn ju ti ìgbà tí mi ò tíì kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́?’

2. Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì

(10 min.)

  • Sm 17:8—Kí ló túmọ̀ sí tí Bíbélì bá lo ọ̀rọ̀ náà “ọmọlójú”? (it-2 714)

  • Àwọn ẹ̀kọ́ iyebíye wo lo rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí tí wàá fẹ́ sọ?

3. Bíbélì Kíkà

TẸRA MỌ́ IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ

4. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa

(1 min.) ÌWÀÁSÙ ILÉ-DÉ-ILÉ. Fún ẹni náà ní ìwé tá a fi ń pe àwọn èèyàn sí Ìrántí Ikú Kristi. (th ẹ̀kọ́ 11)

5. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa

(3 min.) ÌWÀÁSÙ ILÉ-DÉ-ILÉ. Fún ẹni náà ní ìwé tá a fi ń pe àwọn èèyàn sí Ìrántí Ikú Kristi. Ẹni náà gbádùn ọ̀rọ̀ ẹ. Lẹ́yìn náà, fi fídíò Ìrántí Ikú Jésù hàn án, kẹ́ ẹ sì jíròrò ẹ̀. (th ẹ̀kọ́ 9)

6. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa

(2 min.) ÌWÀÁSÙ ÀÌJẸ́-BÍ-ÀṢÀ. Fún ẹni náà ní ìwé tá a fi ń pe àwọn èèyàn sí Ìrántí Ikú Kristi. (th ẹ̀kọ́ 2)

7. Sọ Àwọn Èèyàn Di Ọmọ Ẹ̀yìn

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Orin 20

8. Báwo La Ṣe Lè Múra Sílẹ̀ fún Ìrántí Ikú Kristi?

(15 min.) Ìjíròrò.

Bí Jésù ṣe pa á láṣẹ, a máa ṣe Ìrántí Ikú Kristi ní Sunday, March 24, ìyẹn á jẹ́ ká lè mọrírì ìfẹ́ tó ga jù tí Jèhófà àti Jésù fi hàn sí wa. (Lk 22:19; Jo 3:16; 15:13) Báwo la ṣe lè múra sílẹ̀ fún ètò pàtàkì yìí?

  • Ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe láti pe àwọn èèyàn sí àkànṣe àsọyé àti Ìrántí Ikú Jésù. O lè kọ orúkọ àwọn tó o fẹ́ pè sílẹ̀, kó o sì rí i dájú pé o pè wọ́n. Tó o bá pàdé ẹni tó ń gbé níbi tó jìnnà, lọ sórí jw.org kó o lè wo ibi tí wọ́n á ti ṣe Ìrántí Ikú Kristi ládùúgbò ẹ̀ àti àkókò tí wọ́n á ṣe é

  • O lè ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù lóṣù March àti April. O tiẹ̀ lè ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ kó o sì ròyìn wákàtí mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15) tàbí ọgbọ̀n (30) wákàtí

  • Tó bá di March 18, bẹ̀rẹ̀ sí í ka àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó wáyé ní ọ̀sẹ̀ tí Jésù lò kẹ́yìn láyé. Lójoojúmọ́, o lè pinnu bó o ṣe máa ka ohun tó wà ní apá tá a pè ní “Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Bíbélì Kíkà Lásìkò Ìrántí Ikú Kristi Ọdún 2024” tó wà lójú ìwé 6 àti 7

  • Wo àkànṣe Ìjọsìn Òwúrọ̀ lórí jw.org lọ́jọ́ Ìrántí Ikú Kristi

  • Lọ́jọ́ Ìrántí Ikú Kristi, kí àwọn àlejò káàbọ̀ tọ̀yàyàtọ̀yàyà, ì báà jẹ́ àwọn tó wá nígbà àkọ́kọ́ tàbí àwọn aláìṣiṣẹ́mọ́. Kí wọn dáadáa lẹ́yìn ìpàdé náà, kó o sì bi wọ́n bóyá wọ́n ní ìbéèrè èyíkéyìí. Ṣètò bó o ṣe máa kàn sí wọn nígbà míì kẹ́ ẹ lè máa bá ìjíròrò náà lọ

  • Máa ronú lórí ìràpadà náà ṣáájú àti lẹ́yìn Ìrántí Ikú Kristi

Jẹ́ kí àwọn ará wo FÍDÍÒ Ìrántí Ikú Jésù. Lẹ́yìn náà, béèrè pé:

Báwo la ṣe lè lo fídíò yìí nígbà tá a bá ń pe àwọn èèyàn síbi Ìrántí Ikú Kristi?

9. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ

Ọ̀rọ̀ Ìparí (3 min.) | Orin 73 àti Àdúrà