April 14-20
ÒWE 9
Orin 56 àti Àdúrà | Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)
1. Jẹ́ Ọlọgbọ́n, Má Ṣe Jẹ́ Afiniṣẹ̀sín
(10 min.)
Afiniṣẹ̀sín kì í gba ìmọ̀ràn, ṣe ló máa ń bínú sí ẹni tó bá fún un nímọ̀ràn (Owe 9:7, 8a; w22.02 9 ¶4)
Ọlọgbọ́n máa ń mọyì ìmọ̀ràn tí wọ́n bá fún un, ó sì máa ń mọyì ẹni tó fún un nímọ̀ràn náà (Owe 9:8b, 9; w22.02 12 ¶12-14; w01 5/15 30 ¶1-2)
Ọgbọ́n máa ń ṣeni láǹfààní, àmọ́ ìyà máa ń jẹ afiniṣẹ̀sín (Owe 9:12; w01 5/15 30 ¶5)
2. Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
(10 min.)
Owe 9:17—Kí ni ọ̀rọ̀ náà “omi tí a jí gbé” túmọ̀ sí, kí sì nìdí tó fi máa ń “dùn”?(w06 9/15 17 ¶5)
Àwọn ẹ̀kọ́ iyebíye wo lo rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí tí wàá fẹ́ sọ?
3. Bíbélì Kíkà
(4 min.) Owe 9:1-18 (th ẹ̀kọ́ 5)
4. Pa Dà Lọ
(4 min.) ÌWÀÁSÙ ILÉ-DÉ-ILÉ. Ẹni náà wá sí Ìrántí Ikú Kristi. (lmd ẹ̀kọ́ 8 kókó 3)
5. Pa Dà Lọ
(4 min.) ÌWÀÁSÙ NÍBI TÍ ÈRÒ PỌ̀ SÍ. Nígbà tó o kọ́kọ́ pàdé ẹni náà, o jẹ́ kó mọ ibi tí wọ́n ti máa ṣe Ìrántí Ikú Kristi ládùúgbò ibi tó ń gbé. (lmd ẹ̀kọ́ 7 kókó 4)
6. Pa Dà Lọ
(4 min.) ÌWÀÁSÙ ÀÌJẸ́-BÍ-ÀṢÀ. O ti jẹ́ kí mọ̀lẹ́bí rẹ kan mọ ibi tí wọ́n ti máa ṣe Ìrántí Ikú Kristi ládùúgbò ibi tó ń gbé. (lmd ẹ̀kọ́ 8 kókó 4)
Orin 84
7. Ṣé Àǹfààní Iṣẹ́ Ìsìn Tẹ́ Ẹ Ní Fi Hàn Pé Ẹ Sàn Ju Àwọn Míì Lọ?
(15 min.) Ìjíròrò.
Jẹ́ káwọn ará wo FÍDÍÒ náà. Lẹ́yìn náà, béèrè pé:
Kí ni ọ̀rọ̀ náà “àǹfààní” túmọ̀ sí?
Ojú wo ló yẹ káwọn tó ní àǹfààní iṣẹ́ ìsìn nínú ìjọ máa fi wo ara wọn?
Kí nìdí tó fi jẹ́ pé ká ṣiṣẹ́ sin àwọn míì ṣe pàtàkì ju ká wà ní ipò kan lọ?
8. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ
(30 min.) bt orí 25 ¶5-7, àpótí ojú ìwé 200