April 21-27
ÒWE 10
Orin 76 àti Àdúrà | Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)
1. Kí Ló Ń Jẹ́ Kéèyàn Ní Ọrọ̀ Tòótọ́?
(10 min.)
Tá a bá ń “ṣiṣẹ́ kára” láti jẹ́ káwọn èèyàn mọ Jèhófà, àá di ọlọ́rọ̀ lójú Ọlọ́run(Owe 10:4, 5; w01 7/15 25 ¶1-3)
Kéèyàn jẹ́ olódodo ṣe pàtàkì ju kéèyàn kó nǹkan ìní jọ (Owe 10:15, 16; w01 9/15 24 ¶3-4)
Ìbùkún Jèhófà ló ń sọni di ọlọ́rọ̀ (Owe 10:22; it-1 340)
2. Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
(10 min.)
-
Owe 10:22—Tó bá jẹ́ pé Jèhófà kì í fi ìrora kún ìbùkún rẹ̀, kí wá nìdí táwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ fi máa ń ní ọ̀pọ̀ ìṣòro? (w06 5/15 30 ¶18)
-
Àwọn ẹ̀kọ́ iyebíye wo lo rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí tí wàá fẹ́ sọ?
3. Bíbélì Kíkà
(4 min.) Owe 10:1-19 (th ẹ̀kọ́ 10)
4. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa
(4 min.) ÌWÀÁSÙ ILÉ-DÉ-ILÉ. Ẹni náà sọ pé òun ò gba Ọlọ́run gbọ́. (lmd ẹ̀kọ́ 4 kókó 3)
5. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa
(4 min.) ÌWÀÁSÙ ÀÌJẸ́-BÍ-ÀṢÀ. Bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.(lmd ẹ̀kọ́ 4 kókó 4)
6. Pa Dà Lọ
(4 min.) ÌWÀÁSÙ ÀÌJẸ́-BÍ-ÀṢÀ. Jẹ́ kí ẹni náà rí bó ṣe lè wá ohun tó bá wù ú lórí ìkànnì jw.org. (lmd ẹ̀kọ́ 9 kókó 4)
Orin 111
7. Báwo Làwọn Ìbùkún Jèhófà Ṣe Ń Jẹ́ Káwọn Ìránṣẹ́ Ẹ̀ Láyọ̀?
(7 min.) Ìjíròrò.
Láwọn ọjọ́ ìkẹyìn tí nǹkan le yìí, Jèhófà máa ń bù kún àwọn ìránṣẹ́ ẹ̀, ìyẹn ló sì ń jẹ́ ká lè fara dà á ká sì máa láyọ̀. (Sm 4:3; Owe 10:22) Ka àwọn ẹsẹ Bíbélì yìí. Lẹ́yìn náà, ní káwọn ará sọ bí ìbùkún tó wà nínú àwọn ẹsẹ Bíbélì yìí ṣe ń jẹ́ ká láyọ̀.
Àwọn kan ti fi kún ohun tí wọ́n ń ṣe nínú ìjọsìn Ọlọ́run, ìyẹn sì ń jẹ́ kí wọ́n túbọ̀ láyọ̀.
Jẹ́ káwọn ará wo FÍDÍÒ Ẹ̀yin Ọ̀dọ́—Ẹ Fi Ayé Yín Ṣe Ohun Táá Jẹ́ Kí Ọkàn Yín Balẹ̀! Lẹ́yìn náà, béèrè pé:
-
Kí lo rí kọ́ lára Harley, Anjil, àti Carlee?
8. Ìròyìn Ẹ̀ka Tó Ń Yàwòrán Ilé Tó sì Ń Kọ́ Ọ ti Ọdún 2025
(8 min.) Àsọyé. Jẹ́ kí àwọn ará wo FÍDÍÒ náà.
9. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ
(30 min.) bt orí 25 ¶8-13, àpótí ojú ìwé 201