April 28–May 4
ÒWE 11
Orin 90 àti Àdúrà | Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)
1. Má Ṣe Sọ Ọ̀rọ̀ Tí Kò Yẹ!
(10 min.)
Má ṣe sọ ọ̀rọ̀ tó máa ba “ọmọnìkejì” rẹ lórúkọ jẹ́ (Owe 11:9; w02 5/15 26 ¶4)
Má ṣe sọ ọ̀rọ̀ tó máa da àárín àwọn èèyàn rú (Owe 11:11; w02 5/15 27 ¶2-3)
Má ṣe sọ ọ̀rọ̀ àṣírí síta (Owe 11:12, 13; w02 5/15 27 ¶5)
RONÚ LÓRÍ ÌBÉÈRÈ YÌÍ: Báwo ni ohun tí Jésù sọ ní Lúùkù 6:45 ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ ká má bàa sọ ohun tí kò dáa nípa àwọn ẹlòmíì?
2. Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
(10 min.)
-
Owe 11:17—Àǹfààní wo la máa rí tá a bá jẹ́ onínúure? (g20.1 11, àpótí)
-
Àwọn ẹ̀kọ́ iyebíye wo lo rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí tí wàá fẹ́ sọ?
3. Bíbélì Kíkà
(4 min.) Owe 11:1-20 (th ẹ̀kọ́ 5)
4. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa
(4 min.) ÌWÀÁSÙ ÀÌJẸ́-BÍ-ÀṢÀ. Lo àǹfààní tó yọ láti sọ ohun tó o kọ́ nípàdé lẹ́nu àìpẹ́ yìí fún ẹnì kan. (lmd ẹ̀kọ́ 2 kókó 4)
5. Pa Dà Lọ
(4 min.) ÌWÀÁSÙ ÀÌJẸ́-BÍ-ÀṢÀ. Fi ọ̀kan lára àwọn fídíò tó wà nínú Àpótí Ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ han ẹni náà. (lmd ẹ̀kọ́ 8 kókó 3)
6. Sọ Àwọn Èèyàn Di Ọmọ Ẹ̀yìn
(4 min.) ÌWÀÁSÙ NÍBI TÍ ÈRÒ PỌ̀ SÍ. Bi ẹni náà bóyá ó máa fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, kó o sì fi bá a ṣe ń ṣe é hàn án. (lmd ẹ̀kọ́ 10 kókó 3)
Orin 157
7. Má Ṣe Fi Ọ̀rọ̀ Ẹnu Rẹ Dá Wàhálà Sílẹ̀
(15 min.) ìjíròrò.
A máa ń ṣi ọ̀rọ̀ sọ nígbà míì torí pé aláìpé ni wá. (Jem 3:8) Àmọ́, tá a bá fi sọ́kàn pé ọ̀rọ̀ ẹnu wa lè dá wàhálà sílẹ̀, á jẹ́ ká máa ṣọ́ ohun tá à ń sọ ká má bàa sọ ohun tá a máa kábàámọ̀. Díẹ̀ rèé lára àwọn ọ̀rọ̀ tó lè dá wàhálà sílẹ̀ nínú ìjọ:
-
Kéèyàn máa fọ́nnu. Ẹni tó bá ń fọ́nnu lè mú káwọn míì máa jowú tàbí kí wọ́n máa bá ara wọn díje.—Owe 27:2
-
Ọ̀rọ̀ tí kì í ṣe òótọ́. Èyí kọjá kéèyàn kàn máa parọ́, ó tún kan kéèyàn mọ̀ọ́mọ̀ sọ ohun tó máa ṣi àwọn míì lọ́nà. Kódà kó jẹ́ ìwà àìṣòótọ́ tó dà bíi pé kò tó nǹkan la hù, ó lè bà wá lórúkọ jẹ́ káwọn èèyàn má sì fọkàn tán wa mọ́.—Onw 10:1
-
Òfófó. Ẹni tó bá ń ṣòfófó máa ń tojú bọ ọ̀rọ̀ tí kò kàn án nípa ìgbésí ayé àwọn ẹlòmíì. Ohun tó máa ń sọ nípa àwọn èèyàn lè má jẹ́ òótọ́ délẹ̀délẹ̀ tàbí kó máa sọ ọ̀rọ̀ àṣírí wọn. (1Ti 5:13) Irú nǹkan bẹ́ẹ̀ lè dìjà kó sì da àárín àwọn èèyàn rú
-
Ọ̀rọ̀ téèyàn fìbínú sọ. Èyí ni ọ̀rọ̀ tí kò dáa téèyàn sọ láìronú sẹ́ni tó múnú bí i. (Ef 4:26) Irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ máa ń dunni.—Owe 29:22
Jẹ́ káwọn ará wo FÍDÍÒ Ẹ Yẹra fún Ohun Tó Lè Ba Àlàáfíà Jẹ́—Àyọlò. Lẹ́yìn náà, béèrè pé:
-
Kí lo rí kọ́ nípa ìdí tó fi yẹ ká kíyè sí ohun tá à ń sọ?
Tó o bá fẹ́ mọ ohun tí wọ́n ṣe tí àlàáfíà fi pa dà wà láàárín wọn, wo fídíò ‘Máa Wá Àlàáfíà, Kó O sì Máa Lépa Rẹ̀.’
8. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ
(30 min.) bt orí 25 ¶14-21