March 17-23
ÒWE 5
Orin 122 àti Àdúrà | Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)
1. Sá fún Ìṣekúṣe, Má Tiẹ̀ Sún Mọ́ Ọn Rárá
(10 min.)
Kì í rọrùn láti sá fún ìṣekúṣe (Owe 5:3; w00 7/15 29 ¶1)
Àbámọ̀ ló máa ń gbẹ̀yìn ìṣekúṣe(Owe 5:4, 5; w00 7/15 29 ¶2)
Sá fún ìṣekúṣe, má tiẹ̀ sún mọ́ ọn rárá (Owe 5:8; w00 7/15 29 ¶5)
2. Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
(10 min.)
-
Owe 5:9—Báwo ni ẹni tó ń ṣe ìṣekúṣe ṣe ń fi ‘iyì ara rẹ̀ fún àwọn ẹlòmíì’? (w00 7/15 29 ¶7)
-
Àwọn ẹ̀kọ́ iyebíye wo lo rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí tí wàá fẹ́ sọ?
3. Bíbélì Kíkà
(4 min.) Owe 5:1-23 (th ẹ̀kọ́ 5)
4. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa
(3 min.) ÌWÀÁSÙ NÍBI TÍ ÈRÒ PỌ̀ SÍ. Pe ẹnì kan tí kì í ṣe Kristẹni wá sí Ìrántí Ikú Kristi, kó o sì fi ìkànnì jw.org wá ibi tá a ti máa ṣe é ládùúgbò ẹ̀. (lmd ẹ̀kọ́ 6 kókó 4)
5. Pa Dà Lọ
(4 min.) ÌWÀÁSÙ ILÉ-DÉ-ILÉ. Pa dà lọ sọ́dọ̀ ẹni tó lóun fẹ́ mọ̀ sí i nígbà tó o fún un ní ìwé tá a fi ń pe àwọn èèyàn sí Ìrántí Ikú Kristi. (lmd ẹ̀kọ́ 9 kókó 5)
6. Sọ Àwọn Èèyàn Di Ọmọ Ẹ̀yìn
(5 min.) lff kókó pàtàkì ní ẹ̀kọ́ 16, kí lo rí kọ́? àti ohun tó yẹ kó o ṣe. Ẹni náà béèrè bóyá Jésù níyàwó. Fi bó ṣe lè ṣèwádìí hàn án. (lmd ẹ̀kọ́ 11 kókó 4)
Orin 121
7. Ohun Tẹ́ Ẹ Lè Ṣe Kẹ́ Ẹ Má Bàa Ṣe Ìṣekúṣe Tẹ́ Ẹ Bá Ń Fẹ́ra Sọ́nà
(15 min.) Ìjíròrò.
“Tí ọkùnrin kan àti obìnrin kan bá jọ ń jáde, tí wọ́n sì jọ ń ṣe nǹkan pa pọ̀ torí pé ọkàn wọn ń fà síra,” wọ́n ti ń fẹ́ra sọ́nà nìyẹn. Nígbà míì, wọ́n lè jáde pẹ̀lú àwọn míì tàbí kí wọ́n jáde láwọn nìkan. Nígbà míì sì rèé, wọ́n máa ń bá ara wọn sọ̀rọ̀ lójúkojú tàbí lórí fóònù, wọ́n sì lè máa fọ̀rọ̀ ránṣẹ́ síra wọn. Ìfẹ́sọ́nà kì í ṣọ̀rọ̀ ṣeréṣeré o, kàkà bẹ́ẹ̀ ó máa ń jẹ́ káwọn méjì lè mọ̀ bóyá àwọn máa lè fẹ́ra wọn. Yálà àwọn tó ń fẹ́ra sọ́nà jẹ́ ọ̀dọ́ tàbí àgbàlagbà, àwọn nǹkan wo ló yẹ kí wọ́n ṣe kí wọ́n má bàa ṣe ìṣekúṣe?—Owe 22:3.
Jẹ́ kí àwọn ará wo FÍDÍÒ Bó O Ṣe Lè Múra Sílẹ̀ fún Ìgbéyàwó—Apá 1: Ṣó Ti Yẹ Kí N Lẹ́ni Tí Mò Ń Fẹ́?—Àyọlò. Lẹ́yìn náà, béèrè pé:
-
Kí nìdí tí kò fi yẹ kẹ́nì kan ní àfẹ́sọ́nà tí kò bá tíì ṣe tán láti ṣègbéyàwó? (Owe 13:12; Lk 14:28-30)
-
Kí lo nífẹ̀ẹ́ sí nínú bí àwọn òbí yẹn ṣe ran ọmọ wọn lọ́wọ́?
Ka Òwe 28:26. Lẹ́yìn náà, béèrè pé:
-
Kí làwọn tó ń fẹ́ra sọ́nà lè ṣe kí wọ́n má bàa bá ara wọn ní ipò tó lè mú kí wọ́n ṣe ìṣekúṣe?
-
Kí nìdí tó fi yẹ káwọn tó ń fẹ́ra sọ́nà jọ sọ̀rọ̀ nípa ohun tí wọn ò ní ṣe lórí àwọn ọ̀rọ̀ bíi dídi ara wọn lọ́wọ́ mú, fífi ẹnu ko ara wọn lẹ́nu àtàwọn ọ̀nà míì tí wọ́n lè gbà fìfẹ́ hàn síra wọn?
Ka Éfésù 5:3, 4. Lẹ́yìn náà, béèrè pé:
-
Kí ló yẹ káwọn tó ń fẹ́ra wọn sọ́nà fi sọ́kàn tí wọ́n bá ń bá ara wọn sọ̀rọ̀ lórí fóònù tàbí lórí ìkànnì?
8. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ
(30 min.) bt orí 24 ¶1-6