Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lò
ILÉ ÌṢỌ́
Béèrè ìbéèrè: Ǹjẹ́ ìlérí yìí máa ṣẹ láéláé?
Ka Bíbélì: Iṣi 21:3, 4
Fi ìwé lọni: Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ yìí sọ nípa bí Ọlọ́run ṣe máa mú ìlérí yìí ṣẹ àti àǹfààní tó máa ṣe fún yín.
ILÉ ÌṢỌ́ (ẹ̀yìn ìwé)
Béèrè ìbéèrè: Ẹ jọ̀wọ́, ẹ wo ìbéèrè yìí. [Fi ìbéèrè àkọ́kọ́ tó wà nínú àpilẹ̀kọ tó wà lójú ìwé 16 hàn án àti àwọn ìdáhùn tó wà níbẹ̀.] Kí ni èrò yín nípa rẹ̀?
Ka Bíbélì: Sm 83:18
Fi ìwé lọni: Àpilẹ̀kọ yìí sọ púpọ̀ sí i nípa ohun tí Bíbélì sọ nípa orúkọ Ọlọ́run.
BÍBÉLÌ FI KỌ́NI
Béèrè ìbéèrè: Àwọn kan rò pé Ọlọ́run ló ń darí ayé. Àmọ́ ǹjẹ́ ẹ mọ̀ pé ohun tí Bíbélì sọ kọ́ nìyẹn?
Ka Bíbélì: 1Jo 5:19
Fi ìwé lọni: Ìwé yìí ṣe àlàyé tó ṣe kedere nípa ohun tí Bíbélì fi kọ́ni gan-an lórí kókó yìí àtàwọn kókó míì.
KỌ Ọ̀NÀ ÌGBỌ́RỌ̀KALẸ̀ RẸ
Wo àwọn ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tá a fi ṣe àpẹẹrẹ yìí, kó o sì kọ ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tìrẹ.