Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Àwọn Ọ̀nà Tó O Lè Gbà Lo Ètò Ìṣiṣẹ́ JW Library

Àwọn Ọ̀nà Tó O Lè Gbà Lo Ètò Ìṣiṣẹ́ JW Library

NÍGBÀ ÌDÁKẸ́KỌ̀Ọ́:

  • Ka Bíbélì àti ẹsẹ ojoojúmọ́

  • Ka Ìwé Ọdọọdún, ìwé ìròyìn àtàwọn ìtẹ̀jáde míì. Máa lo ohun tá a pè ní bookmark, èyí tó o lè fi ṣàmì síbi tó o dé

  • Múra ìpàdé sílẹ̀, kó o sì fa ìlà sí ìdáhùn nínú ìtẹ̀jáde tó o fi ń múra ìpàdé sílẹ̀ lórí JW Library

  • Wo fídíò lórí rẹ̀

NÍ ÌPÀDÉ:

  • Ṣí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí alásọyé bá pè. O lè tẹ àmì táá jẹ́ kó o lè pa dà síbi tí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan tó o ṣì tẹ́lẹ̀ wà

  • Dípò tí wàá fi kó ọ̀pọ̀ ìwé tá a máa lò nípàdé dání, ńṣe ni wàá kàn máa ṣí èyí tó o fẹ́ lò nípàdé lórí fóònú tàbí tablet rẹ, wàá sì lè kọrin lórí rẹ̀. Àwọn orin tuntun tí kò tíì sí nínú ìwé orin tá a tẹ̀ jáde ti wà lórí ètò ìṣiṣẹ́ JW Library

LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ:

  • Fi ohun kan látinú ètò ìṣiṣẹ́ JW Library tó wà lórí fóònù tàbí tablet rẹ han ẹnì kan tó nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ rẹ, kó o sì bá a fi JW Library àtàwọn ìtẹ̀jáde sórí fóònù tàbí tablet rẹ̀

  • O lè fi ohun kan tá a ṣe sínú JW Library wá ẹsẹ Bíbélì kan. Tí kò bá gbé ọ̀rọ̀ tàbí àpólà ọ̀rọ̀ tí ò ń wá jáde nínú Bíbélì New World Translation tá a tún ṣe lédè Gẹ̀ẹ́sì, o lè lọ wá a nínú Reference Bible

  • Jẹ́ kí onílé wo fídíò kan. Tí onílé náà bá láwọn ọmọ, ó lè jẹ́ kí àwọn ọmọ rẹ̀ wo ọ̀kan lára àwọn fídíò Di Ọ̀rẹ́ Jèhófà. Tàbí kó o jẹ́ kó wo fídíò tá a pè ní Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kó O Kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì? Èyí á jẹ́ kó nífẹ̀ẹ́ sí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Tó o bá rí ẹni tó ń sọ èdè míì, jẹ́ kó wo fídíò kan ní èdè rẹ̀

  • Ka ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan fún ẹnì kan ní èdè rẹ̀ tó o ti wà jáde sórí JW Library. Lọ síbi tí Ìwé Mímọ́ tó o fẹ́ kà wà, yan ẹsẹ tó o fẹ́ kà, kó o sì tẹ àmì táá ṣí onírúurú ìtumọ̀ Bíbélì kí ẹni náà lè rí i