May 23 sí 29
SÁÀMÙ 19-25
Orin 116 àti Àdúrà
Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
“Àwọn Àsọtẹ́lẹ̀ Jẹ́ Ká Mọ Púpọ̀ Sí I Nípa Mèsáyà”: (10 min.)
Sm 22:1
—Ó máa dà bíi pé Ọlọ́run ti fi Mèsáyà sílẹ̀ (w11 8/15 ojú ìwé 15 ìpínrọ̀ 16) Sm 22:7, 8
—Wọ́n máa kẹ́gàn Mèsáyà (w11 8/15 ojú ìwé 15 ìpínrọ̀ 13) Sm 22:18
—Wọ́n máa ṣẹ́ kèké lé aṣọ Mèsáyà (w11 8/15 ojú ìwé 15 ìpínrọ̀ 14)
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: (8 min.)
Sm 19:14—Ẹ̀kọ́ pàtàkì wo la lè rí kọ́ nínú ẹsẹ Bíbélì yìí? (w06 5/15 ojú ìwé 19 ìpínrọ̀ 8)
Sm 23:1, 2—Báwo ni Jèhófà ṣe jẹ́ olùṣọ́ àgùntàn tó nífẹ̀ẹ́ wa? (w02 9/15 ojú ìwé 32 ìpínrọ̀ 1 àti 2)
Ẹ̀kọ́ wo ni Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí kọ́ mi nípa Jèhófà?
Àwọn kókó wo látinú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí ni mo lè lò lóde ẹ̀rí?
Bíbélì Kíkà: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Sáàmù 25:1-22
MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ
Nígbà Àkọ́kọ́: (2 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) bh—Ka ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan fún onílé lórí fóònù tàbí tablet rẹ.
Ìpadàbẹ̀wò: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) bh—Fi ohun tá a lè fi ṣe ìwádìí, tó wà nínú JW Library wá ẹsẹ Bíbélì kan tó dáhùn ìbéèrè tí onílé béèrè.
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì: (6 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) bh ojú ìwé 129 sí 130 ìpínrọ̀ 11 àti 12
—Ní ṣókí, fi han ẹni tí ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ bó ṣe lè fi JW Library tó wà lórí fóònú tàbí tablet rẹ̀ múra ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ sílẹ̀.
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Orin 55
“Àwọn Ọ̀nà Tó O Lè Gbà Lo Ètò Ìṣiṣẹ́ JW Library”—Apá Kejì: (15 min.) Ìjíròrò. Jẹ́ kí àwọn ará wo àwọn fídíò méjì tá a pè ní Wa Oríṣiríṣi Ìtumọ̀ Bíbélì Jáde Kó O sì Máa Lò Ó àti Ṣe Ìwádìí Nínú Bíbélì Tàbí Ìtẹ̀jáde Míì, kó o sì jíròrò wọ́n ní ṣókí. Lẹ́yìn náà, jíròrò ìsọ̀rí tó gbẹ̀yìn nínú àpilẹ̀kọ náà. Ní kí àwọn ará sọ àwọn ọ̀nà míì tí wọ́n ti gbà lo JW Library lóde ẹ̀rí.
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: (30 min.) ia orí 16 ìpínrọ̀ 1 sí 15
Àtúnyẹ̀wò àti Ohun Tá A Máa Kọ́ Lọ́sẹ̀ Tó Ń Bọ̀ (3 min.)
Orin 139 àti Àdúrà