May 9 sí 15
SÁÀMÙ 1-10
Orin 99 àti Àdúrà
Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
“Tá A Bá Fẹ́ Wà Ní Àlááfíà Pẹ̀lú Jèhófà, A Ní Láti Bọ̀wọ̀ fún Jésù Ọmọ Rẹ̀”: (10 min.)
[Jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò tá a pe àkọlé rẹ̀ ní Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Sáàmù.]
Sm 2:1-3—Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé àwọn alákòóso máa kórìíra Jèhófà àti Jésù (w04 7/15 ojú ìwé 16 àti 17 ìpínrọ̀ 4 sí 8; it-1-E ojú ìwé 507; it-2-E ojú ìwé 386 ìpínrọ̀ 3)
Sm 2:8-12—Awọn tó bá bọ̀wọ̀ fún Ọba tí Jèhófà fòróró yàn nìkan ni yóò ní ìyè (w04 8/1 ojú ìwé 5 ìpínrọ̀ 2 àti 3)
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: (8 min.)
Bíbélì Kíkà: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Sáàmù 8:1–9:10
MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ
Nígbà Àkọ́kọ́: (2 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Àwòrán iwájú ìwé ìròyìn wp16.3—Ka ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan fún onílé lórí fóònú tàbí tablet rẹ.
Ìpadàbẹ̀wò: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Àwòrán iwájú ìwé ìròyìn wp16.3—Kí onílé sọ pé òun ò fẹ́ kó o ka Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun, kó o wá ka ìtumọ̀ Bíbélì míì lórí JW Library.
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì: (6 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) bh ojú ìwé 12 ìpínrọ̀ 12 àti 13—Gba ẹni tí ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ níyànjú pé kó fi JW Library sórí fóònú tàbí tablet rẹ̀.
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Máa Bọ̀wọ̀ fún Ilé Jèhófà: (5 min.) Ìjíròrò. Jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò tó wà lórí ìkànnì jw.org/yo tá a pè ní Di Ọ̀rẹ́ Jèhófà—Máa Bọ̀wọ̀ fún Ilé Jèhófà. (Lọ sí Ẹ̀KỌ́ BÍBÉLÌ > ÀWỌN ỌMỌDÉ.) Lẹ́yìn náà, pe àwọn ọmọdé wá sórí pèpéle, kó o sì bi wọ́n láwọn ìbéèrè díẹ̀ nípa fídíò náà.
Orúkọ Ọlọ́run Nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù: (10 min.) Àsọyé tó dá lórí apá 1 nínú ìwé Àfikún Ìsọfúnni Láti Lóye Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: (30 min.) ia orí 15 ìpínrọ̀ 1 sí 14 àti àpótí tó wà lójú ìwé 138
Àtúnyẹ̀wò àti Ohun Tá A Máa Kọ́ Lọ́sẹ̀ Tó Ń Bọ̀ (3 min.)
Orin 11 àti Àdúrà