ÌWÉ ÌPÀDÉ ÌGBÉSÍ AYÉ ÀTI IṢẸ́ ÒJÍṢẸ́ ÀWA KRISTẸNI May 2018
Ohun Tá A Lè Bá Àwọn Èèyàn Sọ
Ìjíròrò tó dá lórí ọjọ́ iwájú àwa èèyàn àti ilẹ̀ ayé.
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
Gbé Òpó Igi Oró Rẹ, Kí Ó sì Máa Tọ̀ Mí Lẹ́yìn
Kí nìdí tó fi yẹ ká máa gbàdúrà, máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, máa lọ sí òde ẹ̀rí àti ìpàdé déédéé?
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Ran Àwọn Ọmọ Rẹ Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Tẹ̀ Lé Kristi
Kí làwọn òbí lè ṣe láti ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ kí wọ́n lè ya ìgbésí ayé wọn sí mímọ́ fún Jèhófà Ọlọ́run, kí wọ́n sì ṣe ìrìbọmi?
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
Ìran Tó Ń Fún Ìgbàgbọ́ Lókun
Ipa wo ni ìran yìí ní lára àpọ́sítélì Pétérù? Ipa wo ni àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì lè ní lórí àwa náà?
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
“Ohun Tí Ọlọ́rùn Ti So Pọ̀ . . . ”
Àwọn tọkọtaya tó jẹ́ Kristẹni máa ń fi ọwọ́ pàtàkì mú ẹ̀jẹ́ ìgbéyàwó wọn. Àwọn ọkọ àti àwọn aya lè sapá láti fi àwọn ìlànà Bíbélì yanjú àwọn ìṣòro tó bá yọjú.
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
Ó Fi Púpọ̀ Sí I Ju Àwọn Tó Kù Lọ
Ẹ̀kọ́ pàtàkì wo la lè rí kọ́ nínú ìtàn opó tó jẹ́ tálákà tó fi owó tí ìníyelórí rẹ̀ kéré gan-an ṣètọrẹ?
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
Má Ṣe Jẹ́ Kí Ìbẹ̀rù Èèyàn Dẹkùn Mú Ẹ
Kí nìdí táwọn àpọ́sítélì fi bẹ̀rù nígbà tí wọ́n halẹ̀ mọ́ wọn? Lẹ́yìn tí Jésù jíǹde, kí ló ran àwọn àpọ́sítélì tó ti ronú pìwà dà lọ́wọ́ láti wàásù láìfi àtakò pè?
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Jèhófà Á Jẹ́ Kó O Nígboyà
Ṣé ẹ̀rù ti bà ẹ́ rí láti jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni ẹ́? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, báwo lo ṣe lè nígboyà láti bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀?