Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | MÁÀKÙ 9-10

Ìran Tó Ń Fún Ìgbàgbọ́ Lókun

Ìran Tó Ń Fún Ìgbàgbọ́ Lókun

9:1-7

Wo bó ṣe máa rí lára Jésù nígbà tó gbọ́ tí Baba rẹ̀ ọ̀run kéde nínú ìran ológo náà pé òun ti tẹ́wọ́ gbà á. Ó dájú pé ohun tí Ọlọ́run ṣe yìí fún Jésù lókun láti fara da ìyà tó máa tó jẹ. Bákan náà, ìran yìí tún ní ipa tó lágbára lórí Pétérù, Jákọ́bù àti Jòhánù. Ìran náà jẹ́ kó dá wọn lójú pé Jésù ni Mèsáyà lóòótọ́ àti pé ó dáa bí àwọn ṣe fetí sí i. Ní ọdún méjìlélọ́gbọ̀n [32] lẹ́yìn náà, Pétérù ṣì rántí ohun tó rí yẹn àti bí ìran náà ṣe jẹ́ kí ìgbàgbọ́ rẹ̀ nínú “ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀” náà túbọ̀ lágbára sí i.​—2Pe 1:16-19.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a kò fojú rí ìran ológo yẹn, à ń rí bó ṣe ń ní ìmúṣẹ. Jésù ti ń ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí Ọba alágbára. Láìpẹ́, Jésù máa “parí ìṣẹ́gun rẹ̀,” èyí tó máa jẹ́ kí ayé tuntun òdodo wọlé dé.​—Iṣi 6:2.

Báwo ni àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì tó o rí tó ń ṣẹ ṣe fún ìgbàgbọ́ rẹ lókun?