MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
“Ohun Tí Ọlọ́rùn Ti So Pọ̀ . . . ”
Òfin Mósè béèrè pé kí ọkùnrin tó bá ń gbèrò láti kọ ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀ ṣe ìwé ẹ̀rí lọ́nà òfin. Èyí ò ní jẹ́ kí wọ́n lè tètè máa tú ìgbéyàwó wọn ká. Àmọ́, nígbà ayé Jésù, àwọn aṣáájú ẹ̀sìn mú kó rọrùn fáwọn èèyàn láti kọ ara wọn sílẹ̀. Àwọn ọkùnrin lè kọ aya wọn sílẹ̀ lórí ẹ̀sùn èyíkéyìí. (“ìwé ẹ̀rí ìlélọ, kọ aya rẹ̀ sílẹ̀, ṣe panṣágà lòdì sí i” àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Mk 10:4, 11,nwtsty) Jésù pe àfiyèsí sí òkodoro òtítọ́ náà pé Jèhófà ló dá ìgbéyàwó sílẹ̀. (Mk 10:2-12) Ó fẹ́ kí ọkọ àti ìyàwó di “ara kan,” kí wọ́n má sì tú ká. Ìdí kan ṣoṣo tó bá Ìwé Mímọ́ mu, ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí Mátíù sọ tó jọ èyí tí Máàkù náà sọ, tó lè mú kí wọ́n kọ ara wọn sílẹ̀ ni “àgbèrè.”—Mt 19:9.
Lóde òní, kì í ṣe èrò tí Jésù ní nípa ìgbéyàwó ni àwọn èèyàn ní, èrò àwọn Farisí ni wọ́n ní. Kíá làwọn èèyàn inú ayé máa ń kọ ara wọn sílẹ̀ tí wọ́n bá ní ìṣòro nínú ìgbéyàwó wọn. Àmọ́, àwọn tọkọtaya tó jẹ́ Kristẹni máa ń fi ọwọ́ pàtàkì mú ẹ̀jẹ́ ìgbéyàwó wọn, wọ́n sì máa ń sapá láti fi àwọn ìlànà Bíbélì yanjú àwọn ìṣòro tó bá yọjú. Wo fídíò náà Ìfẹ́ àti Ọ̀wọ̀ Ń Mú Kí Ìdílé Wà Níṣọ̀kan, kó o sì dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:
-
Báwo lo ṣe lè fi ohun tó wà ní Òwe 15:1 sílò nínú ìgbéyàwó rẹ, kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì?
-
Báwo lo ṣe lè yẹra fún ìṣòro tó o bá fi ohun tó wà ní Òwe 19:11 sílò?
-
Tó bá jẹ́ pé ìgbéyàwó rẹ ti fẹ́ tú ká, dípò kó o máa ronú pé, ‘Ṣé kí n kọ̀ ọ́ sílẹ̀?’ àwọn ìbéèrè wo ló yẹ kó o ronú lé?
-
Báwo lo ṣe lè jẹ́ ọkọ tàbí aya rere tó o bá fi ohun tó wà ní Mátíù 7:12 sílò?