Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

May 21-​27

Máàkù 11-12

May 21-​27
  • Orin 34 àti Àdúrà

  • Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

  • Ó Fi Púpọ̀ Sí I Ju Àwọn Tó Kù Lọ”: (10 min.)

    • Mk 12:​41, 42​—Jésù ṣàkíyèsí òtòṣì opó kan tó ń sọ ẹyọ owó kéékèèké méjì, tí ìníyelórí wọn kéré gan-an sínú àpótí ìṣúra tó wà nínú tẹ́ńpìlì (“àwọn àpótí ìṣúra,” “ẹyọ owó kéékèèké méjì,” “tí ìníyelórí wọ́n kéré gan-an” àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Mk 12:41, 42, nwtsty)

    • Mk 12:43​—Jésù mọyì ohun tí obìnrin náà ṣe, ó sì tẹnu mọ́ kókó yìí fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ (w97 10/15 16-17 ¶16-17)

    • Mk 12:44​—Ọrẹ tí obìnrin opó yìí ṣe níye lórí gan-an lójú Jèhófà (w97 10/15 17 ¶17; w87 12/1 30 ¶1; cl 185 ¶15)

  • Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: (8 min.)

    • Mk 11:17​—Kí nìdí tí Jésù fi pe tẹ́ńpìlì ní “ilé àdúrà fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè”? (“ilé àdúrà fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè” àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Mk 11:17, nwtsty)

    • Mk 11:27, 28​—“Nǹkan” wo làwọn alátakò Jésù ń tọ́ka sí? (jy 244 ¶7)

    • Kí ni Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí kọ́ ẹ nípa Jèhófà?

    • Àwọn ìṣúra tẹ̀mí wo lo tún rí látinú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí?

  • Bíbélì Kíkà: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Mk 12:​13-27

MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ

  • Nígbà Àkọ́kọ́: (2 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ. Dáhùn ìbéèrè kan táwọn èèyàn sábà máa ń béèrè tí wọn kò bá fẹ́ gbọ́ ìwàásù ní ìpínlẹ̀ yín.

  • Ìpadàbẹ̀wò Àkọ́kọ́: (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ. Ẹni náà sọ fún ẹ pé èèyàn òun kan kú láìpẹ́ yìí.

  • Ìpadàbẹ̀wò Kejì Fídíò: (5 min.) Ẹ wo fídíò náà, kẹ́ ẹ sì jíròrò rẹ̀.

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI