MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Ran Àwọn Ọmọ Rẹ Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Tẹ̀ Lé Kristi
Ohun tó ń fún àwọn òbí tó jẹ́ Kristẹni láyọ̀ tó ga jù ni bí wọ́n ṣe ń rí i pé ọmọ wọn ‘sẹ́ níní ara rẹ̀, ó gbé òpó igi oró rẹ̀, ó sì ń tọ’ Jésù lẹ́yìn. (Mk 8:34; 3Jo 4) Kí làwọn òbí lè ṣe láti ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ kí wọ́n lè máa tẹ̀ lé Jésù, kí wọ́n ya ara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà, kí wọ́n sì ṣe ìrìbọmi? Kí làwọn ọmọ yín ń ṣe tó fi hàn pé wọ́n ti ṣe tán láti ṣe ìrìbọmi?
Ka “Ọ̀rọ̀ Ìyànjú fún Àwọn Òbí” ní ojú ìwé 165 àti 166 nínú ìwé A Ṣètò Wa Láti Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà, kó o sì ronú lórí àwọn ìbéèrè yìí: