Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Máa Fìfẹ́ Hàn Nínú Ìdílé

Máa Fìfẹ́ Hàn Nínú Ìdílé

Ìfẹ́ ló máa ń so àwọn tó wà nínú ìdílé pọ̀. Tí ò bá sí ìfẹ́, ìdílé ò ní wà níṣọ̀kan, wọn ò sì ní fọwọ́sowọ́pọ̀. Báwo làwọn ọkọ, aya àtàwọn òbí ṣe lè máa fìfẹ́ hàn nínú ìdílé?

ọkọ kan bá nífẹ̀ẹ́ ìyàwó ẹ̀, á máa ka ohun tó nílò sí pàtàkì, á máa tẹ́tí sí i, á sì máa gba tiẹ̀ rò. (Ef 5:28, 29) A máa pèsè ohun tí ìdílé rẹ̀ nílò nípa tara àti nípa tẹ̀mí, á sì máa rí i pé òun ń ṣe Ìjọsìn Ìdílé déédéé. (1Ti 5:8) Tí aya kan bá nífẹ̀ẹ́ ọkọ ẹ̀, á máa tẹrí ba fún un, á sì ní “ọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀” fún un. (Ef 5:22, 33; 1Pe 3:1-6) Àwọn méjèèjì gbọ́dọ̀ máa dárí ji ara wọn ní fàlàlà. (Ef 4:32) Òbí tó bá nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ ẹ̀ máa jẹ́ kó dá ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn lójú pé lóòótọ́ lòun nífẹ̀ẹ́ wọn, á sì máa kọ́ wọn láti nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. (Di 6:6, 7; Ef 6:4) Á gbìyànjú láti mọ ohun táwọn ọmọ náà ń kojú nílé ìwé àtohun tí wọ́n ń ṣe táwọn ọ̀rẹ́ wọn bá fẹ́ mú kí wọ́n ṣe ohun tí ò dáa. Tí ìfẹ́ bá wà nínú ìdílé, gbogbo àwọn tó wà nínú ìdílé náà lọ́kàn wọn máa balẹ̀.

Ẹ WO FÍDÍÒ NÁÀ MÁA FI ÌFẸ́ TI KÌ Í YẸ̀ HÀN NÍNÚ ÌDÍLÉ, KẸ́ Ẹ SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:

  • Báwo ni ọkọ tó nífẹ̀ẹ́ ìyàwó ẹ̀ á ṣe máa bọ́ ọ, tá sì máa ṣìkẹ́ ẹ̀?

  • Báwo ni ìyàwó tó nífẹ̀ẹ́ ọkọ ẹ̀ ṣe lè fi ọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀ hàn sí i?

  • Báwo làwọn òbí tó nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ wọn ṣe lè máa kọ́ wọn ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run?