Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Ṣe Ìpinnu Tó Bọ́gbọ́n Mu Lórí Ọ̀rọ̀ Ọtí

Ṣe Ìpinnu Tó Bọ́gbọ́n Mu Lórí Ọ̀rọ̀ Ọtí

Gbogbo àwa Kristẹni la gbọ́dọ̀ máa kó ara wa níjàánu tó bá dọ̀rọ̀ ká mutí. (Owe 23:20, 29-35; 1Kọ 6:9, 10) Tí Kristẹni kan bá pinnu láti mutí, ó gbọ́dọ̀ mu ún níwọ̀ntúnwọ̀nsì. Ó tún gbọ́dọ̀ ṣọ́ra kí ọtí má bàa di bárakú fún un, kó má sì mú àwọn míì kọsẹ̀. (1Kọ 10:23, 24; 1Ti 5:23) Bákan náà, kò yẹ ká máa ti àwọn míì láti mutí, pàápàá jù lọ àwọn ọ̀dọ́.

Ẹ WO FÍDÍÒ ERÉ OJÚ PÁTÁKÓ NÁÀ MÁ ṢE JẸ́ KÍ ỌTÍ DI ÌDẸKÙN FÚN Ẹ, KẸ́ Ẹ SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:

  • Kí nìdí tó fi yẹ káwa Kristẹni máa pa òfin ìjọba mọ́ lórí ọ̀rọ̀ ọtí mímu?​—Ro 13:1-4

  • Kí nìdí tí kò fi yẹ ká jẹ́ káwọn míì tì wá láti mutí?​—Ro 6:16

  • Kí la lè ṣe láti yẹra fún ewu tó ní ín ṣe pẹ̀lú ọtí mímu?