ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
“Kí Ni Jèhófà Ọlọ́run Rẹ Fẹ́ Kó O Ṣe?”
Máa ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́ torí pé o bẹ̀rù rẹ̀, o sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ (Di 10:12; w09 10/1 10 ¶3-4)
Ọ̀pọ̀ ìbùkún la máa rí tá a bá ń ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́ (Di 10:13; w09 10/1 10 ¶6)
Jèhófà fẹ́ ká sún mọ́ òun (Di 10:15; cl 16 ¶2)
Jèhófà ò fipá mú wa láti ṣe ohun tó fẹ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó fẹ́ ká nífẹ̀ẹ́ òun, ká sì máa ṣègbọràn sí òun “látọkàn wá.” (Ro 6:17) Tá a bá pinnu láti sin Jèhófà, àá gbádùn ìgbésí ayé tó nítumọ̀.