ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
Àwọn Òfin Jèhófà Bọ́gbọ́n Mu, Wọ́n sì Bá Ìdájọ́ Òdodo Mu
A máa fi hàn pé a jẹ́ ọlọ́gbọ́n àti olóye tá a bá ń pa òfin Ọlọ́run mọ́ (Di 4:6; it-2 1140 ¶5)
Ọ̀pọ̀ àwọn tó ń kíyè sí ìwà wa ló gbà pé ó bọ́gbọ́n mu láti máa pa àwọn òfin Ọlọ́run mọ́ lóòótọ́ (Di 4:6; w99 11/1 20 ¶6-7)
Ìgbésí ayé àwa èèyàn Jèhófà máa ń dáa gan-an ju tàwọn èèyàn ayé lọ (Di 4:7, 8; w07 8/1 29 ¶13)
Ìwà wa dáa torí pé à ń tẹ̀ lé àwọn òfin àti ìlànà Jèhófà, ìyẹn sì ti mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn wá sínú ètò Jèhófà.
Àwọn ìbùkún wo lo ti rí torí pé ò ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà Jèhófà?