ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
San Ẹ̀jẹ́ Rẹ
Dandan kọ́ ni káwọn ọmọ Ísírẹ́lì jẹ́jẹ̀ẹ́, àmọ́ tí wọ́n bá ṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n gbọ́dọ̀ san ohun tí wọ́n jẹ́jẹ̀ẹ́ (Nọ 30:2; it-2 1162)
Ẹnì kan lè jẹ́jẹ̀ẹ́ pé òun ò ní ṣe ohun kan bó tiẹ̀ jẹ́ pé kò sófin tó ní kó má ṣe nǹkan náà (Nọ 30:3, 4; it-2 1162)
Lóde òní, ẹnì kọ̀ọ̀kan ló máa pinnu ohun tóun fẹ́ ṣe láti múnú Jèhófà dùn (Nọ 30:6-9; w04 8/1 27 ¶4)
Ẹ̀jẹ́ ìyàsímímọ́ àti ẹ̀jẹ́ ìgbéyàwó ni ẹ̀jẹ́ méjì tó ṣe pàtàkì jù lọ táwa Kristẹni máa ń jẹ́ lónìí.
BI ARA RẸ PÉ, ‘Ṣé mò ń mú ẹ̀jẹ́ mi ṣẹ?’