Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

“Ẹ Lé Gbogbo Àwọn Tó Ń Gbé Ilẹ̀ Náà Kúrò”

“Ẹ Lé Gbogbo Àwọn Tó Ń Gbé Ilẹ̀ Náà Kúrò”

Jèhófà ní káwọn ọmọ Ísírẹ́lì mú ohunkóhun tó bá lè mú kí wọ́n kọsẹ̀ kúrò ní Ilẹ̀ Ìlérí (Nọ 33:52; w10 8/1 23)

Jèhófà ṣèlérí pé òun máa ràn wọ́n lọ́wọ́ láti gba ilẹ̀ náà tí wọ́n bá ṣe gbogbo ohun tóun ní kí wọ́n ṣe (Nọ 33:53)

Nǹkan máa nira fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí wọn ò bá pa gbogbo àwọn ọ̀tá wọn run (Nọ 33:​55, 56; w08 2/15 27 ¶4-5; it-1 404 ¶2)

Tá a bá fẹ́ múnú Jèhófà dùn, a ò gbọ́dọ̀ fàyè gba ohunkóhun tó lè mú ká hùwàkiwà, tó sì lè ba àjọṣe àwa àti Jèhófà jẹ́. (Jem 1:21) Jèhófà máa ràn wá lọ́wọ́ ká lè yẹra fáwọn nǹkan tó lè mú ká dẹ́ṣẹ̀, ká sì borí ẹ̀mí ayé.