MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ | JẸ́ KÍ IṢẸ́ SÍSỌNI DI ỌMỌ Ẹ̀YÌN MÁA FÚN Ẹ LÁYỌ̀
Máa Fi Àpèjúwe Ṣàlàyé Kókó Pàtàkì
Tá a bá ń ṣe ìpadàbẹ̀wò tàbí darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó yẹ ká jẹ́ káwọn èèyàn lóye àwọn kókó pàtàkì tó wà nínú ohun tá à ń kọ́ wọn. Tá a bá fi àpèjúwe ṣàlàyé àwọn kókó pàtàkì yìí, àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ máa nífẹ̀ẹ́ sí ohun tí wọ́n ń kọ́, wọn ò sì ní tètè gbàgbé.
Tó o bá ń múra ìpadàbẹ̀wò tàbí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì sílẹ̀, wá àwọn kókó pàtàkì tó o lè fi àpèjúwe ṣàlàyé. Má ronú jù lórí àwọn kókó tí ò fi bẹ́ẹ̀ pọndandan. Wá àwọn àpèjúwe tó máa rọrùn fún akẹ́kọ̀ọ́ rẹ láti lóye. (Mt 5:14-16; Mk 2:21; Lk 14:7-11) Ronú nípa irú ẹni tó o fẹ́ bá sọ̀rọ̀, iṣẹ́ tó ń ṣe àtàwọn nǹkan míì nípa ẹni náà. (Lk 5:2-11; Jo 4:7-15) Tó o bá rí bínú ẹni tó ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ ṣe dùn torí pé ó lóye kókó pàtàkì kan, ó dájú pé inú tìẹ náà máa dùn.
Ẹ WO FÍDÍÒ NÁÀ JẸ́ KÍ IṢẸ́ SÍSỌNI DI ỌMỌ Ẹ̀YÌN MÁA FÚN Ẹ LÁYỌ̀—TÚBỌ̀ JÁ FÁFÁ—MÁA FI ÀPÈJÚWE ṢÀLÀYÉ KÓKÓ PÀTÀKÌ, KẸ́ Ẹ SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:
-
Kí ló lè mú kó nira fún akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa láti lóye àwọn ẹsẹ Bíbélì kan?
-
Àpèjúwe wo ni Neeta fi ṣàlàyé Róòmù 5:12?
-
Báwo ni àpèjúwe tó dáa ṣe lè ràn àwọn akẹ́kọ̀ọ́ wa lọ́wọ́?
-
Tá a bá ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká máa lo fídíò àtàwọn ohun èlò ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ míì tí ètò Ọlọ́run ṣe?