May 3-9
NỌ́ŃBÀ 27-29
Orin 106 àti Àdúrà
Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
“Yẹra fún Ojúsàájú, Kó O Lè Fìwà Jọ Jèhófà”: (10 min.)
Àwọn Ìṣúra Tẹ̀mí: (10 min.)
Bíbélì Kíkà: (4 min.) Nọ 28:11-31 (th ẹ̀kọ́ 5)
MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ
Fídíò Nígbà Àkọ́kọ́: (5 min.) Ìjíròrò. Jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò Nígbà Àkọ́kọ́: Ohun Tí Ọlọ́run Fẹ́ fún Wa—Jẹ 1:28. Ẹ dá fídíò náà dúró láwọn ibi tẹ́ ẹ bá ti rí ìbéèrè, kẹ́ ẹ sì jíròrò ìbéèrè náà kẹ́ ẹ tó máa wò ó lọ.
Nígbà Àkọ́kọ́: (3 min.) Lo ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ. (th ẹ̀kọ́ 4)
Àsọyé: (5 min.) w07 4/1 17-18—Àkòrí: Kí Lá Mú Kínú Jèhófà Dùn sí Ọrẹ Tàbí Ẹbọ Wa? (th ẹ̀kọ́ 16)
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Di Ọ̀rẹ́ Jèhófà—Nífẹ̀ẹ́ Ọmọnìkejì Rẹ: (6 min.) Ìjíròrò. Jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò náà. Lẹ́yìn náà, tó bá ṣeé ṣe, pe àwọn ọmọdé bíi mélòó kan, kó o sì béèrè àwọn ìbéèrè yìí lọ́wọ́ wọn: Kí nìdí táwọn ọmọléèwé ò fi gba ti Priya? Báwo ni Tósìn ṣe fìfẹ́ hàn sí Priya? Báwo lo ṣe lè fìfẹ́ hàn sáwọn tí àwọ̀ tàbí èdè wọn yàtọ̀ sí tìẹ?
Ta Ni Ọ̀rẹ́ Tòótọ́?: (9 min.) Ìjíròrò. Jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò eré ojú pátákó náà. Lẹ́yìn náà béèrè pé: Kí ló yẹ kó o wò lára ẹni tó o fẹ́ fi ṣọ̀rẹ́? Ibo lo ti lè rí ọ̀rẹ́ gidi? Báwo lo ṣe lè ní ọ̀rẹ́ gidi?
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: (30 min.) rr orí 8 ¶8-15 àti àpótí 8A
Ọ̀rọ̀ Ìparí (3 min.)
Orin 16 àti Àdúrà