MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Múra Sílẹ̀ Ní Apá Ìgbẹ̀yìn “Àwọn Ọjọ́ Ìkẹyìn” Yìí
Ó dá wa lójú pé ṣe ni nǹkan á túbọ̀ máa le sí i bá a ṣe ń sún mọ́ apá ìgbẹ̀yìn “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” yìí. (2Ti 3:1; “wàhálà tó ń fa ìrora” àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Mt 24:8, nwtsty) Tí àjálù bá ṣẹlẹ̀, ètò Ọlọ́run sábà máa ń fún wa láwọn ìtọ́ni tó bọ́ sákòókò, tó sì máa ń dáàbò bò wá. Tá a bá fẹ́ là á já lọ́jọ́ ìwájú, a gbọ́dọ̀ jẹ́ kó mọ́ wa lára ní báyìí láti máa ṣègbọràn sáwọn ìtọ́ni tí ètò Ọlọ́rùn ń fún wa nípa tẹ̀mí àti nípa tara.—Lk 16:10.
-
Múra sílẹ̀ nípa tẹ̀mí: Jẹ́ kó mọ́ ẹ lára láti máa ka Bíbélì déédéé, kó o sì máa dá kẹ́kọ̀ọ́. Máa lo oríṣiríṣi ọ̀nà tí iṣẹ́ ìwàásù pín sí. Má bẹ̀rù tí ipò tó o bá ara ẹ ò bá jẹ́ kó o wà pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn ará. (Ais 30:15) Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Jèhófà àti Jésù wà pẹ̀lú rẹ.—od 176 ¶15-17
-
Múra sílẹ̀ nípa tara: Yàtọ̀ sí báàgì pàjáwìrì, ó tún yẹ kí ìdílé kọ̀ọ̀kan ní ìwọ̀nba oúnjẹ pa mọ́, títí kan omi, oògùn àtàwọn nǹkan míì tí wọ́n máa nílò tí àjálù bá ṣẹlẹ̀, tó sì gba pé kí wọ́n wà níbì kan fún àkókò tó gùn.—Owe 22:3; g17.5 4, 6
Ẹ WO FÍDÍÒ NÁÀ ṢÉ O TI MÚRA SÍLẸ̀ DE ÀJÁLÙ? KẸ́ Ẹ SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:
-
Báwo la ṣe lè múra sílẹ̀ nípa tẹ̀mí fún àjálù?
-
Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé . . .
-
ká fún àwọn alàgbà ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìsọfúnni nípa wa?
-
ká ní báàgì pàjáwìrì?
-
ká jíròrò irú àwọn àjálù tó lè ṣẹlẹ̀ àtohun tá a máa ṣe tí èyíkéyìí nínú wọn bá ṣẹlẹ̀?
-
-
Àwọn nǹkan mẹ́ta wo la lè ṣe tá a bá fẹ́ ṣèrànwọ́ fáwọn tí àjálù ṣẹlẹ̀ sí?
BI ARA RẸ PÉ, ‘Báwo ni àrùn Corona ṣe jẹ́ kí n rí ìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kí n múra sílẹ̀ de àjálù?’