Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Kó Ara Ẹ Níjàánu Tí Èròkerò Bá Ń Wá Sí Ẹ Lọ́kàn

Kó Ara Ẹ Níjàánu Tí Èròkerò Bá Ń Wá Sí Ẹ Lọ́kàn

Aláìpé ni wá, torí náà léraléra ni èròkerò á máa wá sí wa lọ́kàn. Tá a bá fàyè gbà wọ́n, tá a sì jẹ́ kí wọ́n máa darí wa, a lè pàdánù ojúure Jèhófà. Bí àpẹẹrẹ, àwọn kan ti jẹ́ kí ìfẹ́ tí wọ́n ní fún oúnjẹ, aṣọ àti ibùgbé pọ̀ ju ìfẹ́ tí wọ́n ní fún Ọlọ́run lọ. Àwọn míì máa ń wá bí wọ́n á ṣe ní ìbálòpọ̀ láìka ìlànà Ọlọ́run sí rárá. (Ro 1:26, 27) Àwọn kan máa ń jẹ́ káwọn míì sún wọn ṣe ohun tí kò tọ́ káwọn èèyàn lè gba tiwọn.​—Ẹk 23:2.

Kí la lè ṣe tá ò fi ní gba èròkerò láyè nínú ọkàn wa? A gbọ́dọ̀ máa sapá láti ronú nípa àwọn ohun tí inú Jèhófà dùn sí. (Mt 4:4) Bákan náà, ó yẹ ká bẹ Jèhófà pé kó ràn wá lọ́wọ́ láti gbé èròkerò kúrò lọ́kàn. Kí nìdí? Ìdí ni pé Jèhófà mọ ohun tó dáa jù fún wa, ó sì lè pèsè gbogbo ohun tá a nílò.​—Sm 145:16.

Ẹ WO FÍDÍÒ NÁÀ SÌGÁ MÍMU LÈ BA AYÉ ÈÈYÀN JẸ́, KẸ́ Ẹ SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:

  • Kí nìdí táwọn kan fi máa ń mu sìgá?

  • Àkóbá wo ni sìgá mímu lè ṣe fún ẹ?

  • Kí nìdí tí sìgá mímu àti èyí tí wọ́n ń fi páìpù fà fi burú?​—2Kọ 7:1

  • O lè kó ara ẹ níjàánu tó bá ń ṣe ẹ́ bíi pé kó o mu sìgá!

    Kí lo lè ṣe tí wọ́n bá fi sìgá lọ̀ ẹ́? Kí lo sì lè ṣe tó o bá fẹ́ jáwọ́ nínú sìgá mímu?