Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Fi Ìwé Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé! Ran Àwọn Èèyàn Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Nígbàgbọ́ Nínú Jèhófà àti Jésù

Fi Ìwé Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé! Ran Àwọn Èèyàn Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Nígbàgbọ́ Nínú Jèhófà àti Jésù

Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa gbọ́dọ̀ nígbàgbọ́ tó lágbára kí wọ́n tó lè múnú Ọlọ́run dùn. (Heb 11:6) A lè lo ìwé Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé! láti mú kí ìgbàgbọ́ wọn lágbára. Lára àwọn ohun tó wà nínú ìwé yìí ni àwọn ẹsẹ Bíbélì tó ṣe ṣàkó, àwọn àlàyé tó ṣe kedere, àwọn ìbéèrè tó ń múni ronú jinlẹ̀, àwọn fídíò tó ń wọni lọ́kàn àtàwọn àwòrán tó rẹwà. Tá a bá ń ran àwọn akẹ́kọ̀ọ́ wa lọ́wọ́ láti ní àwọn ìwà tó yẹ Kristẹni, kó sì ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà, ṣe ló máa dà bí ìgbà tá à ń fi ohun èlò tí iná ò lè bà jẹ́ kọ́ ilé.​—1Kọ 3:12-15.

Àwọn kan ò gbà pé àwọn lè di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run torí pé wọn ò lè rí i. Torí náà, ó yẹ ká ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè mọ Jèhófà, kí wọ́n sì gbẹ́kẹ̀ lé e.

Ẹ WO FÍDÍÒ NÁÀ FI ÌWÉ GBÁDÙN AYÉ RẸ TÍTÍ LÁÉ! RAN ÀWỌN ÈÈYÀN LỌ́WỌ́ KÍ ÌGBÀGBỌ́ WỌN NÍNÚ JÈHÓFÀ LÈ LÁGBÁRA! KẸ́ Ẹ SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:

  • Kí ló jẹ́ ká mọ̀ pé arábìnrin yẹn múra ìkẹ́kọ̀ọ́ náà sílẹ̀ dáadáa?

  • Kí lo rí kọ́ nínú bí arábìnrin náà ṣe lo àwọn ìbéèrè tó ń múni ronú jinlẹ̀ kí akẹ́kọ̀ọ́ náà lè lóye ohun tó wà nínú Àìsáyà 41:10, 13?

  • Báwo ni fídíò àti ẹsẹ Bíbélì yẹn ṣe jẹ́ kí ọ̀rọ̀ náà túbọ̀ wọ akẹ́kọ̀ọ́ náà lọ́kàn?

Ọ̀pọ̀ ò lóye ìdí tá a fi nílò ìràpadà, àwọn míì ò sì gbà pé ẹ̀bùn látọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni. (Ga 2:20) Torí náà, ó ṣe pàtàkì ká ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè nígbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà Jésù.

Ẹ WO FÍDÍÒ NÁÀ FI ÌWÉ GBÁDÙN AYÉ RẸ TÍTÍ LÁÉ! RAN ÀWỌN ÈÈYÀN LỌ́WỌ́ KÍ ÌGBÀGBỌ́ WỌN NÍNÚ JÉSÙ LÈ LÁGBÁRA! KẸ́ Ẹ SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:

  • Kí ló jẹ́ ká mọ̀ pé arákùnrin yẹn múra ìkẹ́kọ̀ọ́ náà sílẹ̀ dáadáa?

  • Báwo ni arákùnrin náà ṣe lo apá tá a pè ní “Ṣèwádìí” láti ran akẹ́kọ̀ọ́ ẹ̀ lọ́wọ́?

  • Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì kí akẹ́kọ̀ọ́ náà gbàdúrà?